Food Festival: Ìbọn pa èèyàn mẹ́ta níbí ayẹyẹ Oúnjẹ ní Carlifornia

Carlifornia Image copyright EPA

Eeyan mẹta lo ti gbẹmi mi gẹgẹ bi agbebọn kan ṣe ṣina ibọn bolẹ nibi ayẹyẹ ọdun ounjẹ kan to n waye niluu Carlifornia.

Amọ agbebọn naa ko ye e tori awọn ọlọpaa naa doju ibọn kọ lẹyin to ṣina ibọn tirẹ bolẹ.

Awọn ọlọpaa ṣi n ṣewadii awn iroyin to sọ pe afurasi agbebọn ṣi ku ọkan ti wọn ko si ti mọ ibi ti o wa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionShiite: Ẹ̀mí àti ara wa kọ ohun tí ìjọba ń ṣe sìwa láti 2015

Ayẹyẹ Ọdun Gilroy Garlic ti n sun mọ bebe ipari lopin ọsẹ naa lọjọ aiku nigba ti wọn da ibọn bolẹ nibi eto naa.

Stephen Romero ọmọ ọdun mẹfa ni ẹni ti wọn ri ti ẹmi rẹ kọkọ ba iṣẹlẹ naa rin. Baba rẹ ati iya rẹ na fara pa.

"Mi o fẹ gba ohun to n ṣẹlẹ gbọ nigba ti iyawo mi sọ fun mi, irọ ni mo pe e tabi mo n la ala" ni Ọgbẹni romero sọ.

Inú mi dùn pé ẹni tó gbà ìjọba lọ́wọ́ mi ń san gbèsè tí mo fi kalẹ - Aregbesola

Ilé alájà méjì wó lu ọmọ mẹ́rin ni Bariga

Ipele kan náà kó ní Yorùbá àti ẹgbẹ́ darandaran Miyetti Allah wà- Afẹnifẹre

El-Zakzaky kò fojú hàn nílé ẹ́jọ́ ṣùgbọ́n wọ́n sún ẹjọ́ rẹ̀ síwájú

"Inu ọmọ yii maa n dun ni gbogbo igba lati ṣere, rere lo maa n ro". O fi kun un wi pe wọn ti gbe iya rẹ naa lọ fun itọju pajawiri lẹyin ti ibọn ba a ni ikun ati ẹsẹ.

Eyi ni igba ikẹrindin ni ọgọrun meji ati abọ ti iṣẹlẹ ibọn yinyin nla bayii yoo ṣẹlẹ nilẹ Amẹrika gẹgẹ bi ile iṣẹ to n ṣe ọfintoto iṣẹlẹ ibọn yinyin ṣe jabọ.

Awọn to ṣoju wọn koro ni kan ni o jọ bii pe alawọfunfun ni to wa ni nkan bii ẹni ọgbọn ọdun o ṣẹ le diẹ. O dọgbọn wọ aṣọ bi ologun.

Awọn Iroyin mii ti ẹ le nifẹ si

Afurasi naa gba ara odi ile wọ ibi ayẹyẹ ti wọn n ṣe gẹgẹ bi ọlọpaa ṣe royin. Awọn ọlọpaa kan naa ti wa nibi ayẹyẹ ọhun latilẹ nitori naa, lẹsẹkẹsẹ ni wọn doju ija ni kete ti wọn gburo ibọn laarin iṣẹju akan.

Ati Gomina ilu Carlifornia, Gavin Newsom ati Aarẹ Donald Trump lo fi si oju opo ayelujara wọn pe iṣẹlẹ naa buru jai pe ki awn eniyan si ṣe pẹlẹ.

"Lọtun losi lo n yinbọ, o daju pe o ti gbero bo ṣe fẹ ṣe ọṣẹ naa tẹlẹ. O kan ṣaa jẹ ina ibọn to ya gan gẹgẹ bi ẹlomiran to ṣoju rẹ ṣe sọ ọ."

Ẹwẹ wọn ti gbe awọn to fara pa lọ si ile iwosan fun itọju kanmọkanmọ.