Ibadan NURTW: Àwọn ti Auxilliary àtàwọn tí Ajanaku gangan ló ń dàgboro rú

Ọkọ ero ipinlẹ Ọyọ Image copyright @Oyoaffairs

Awọn olugbe agbegbe Ẹgbẹda nilu Ibadan ti ṣe alaye wi pe igbiyanju awọn alakoso ẹgbẹ awakọ NURTW ipinlẹ Ọyọ lati wa ojutu si ofin ti ijọba fi de wọn lo ṣokunfa rogbodiyan ti o waye ni agbede naa lopin ọsẹ.

Bo tilẹ jẹ wi pe awọn eeyan ti o ba ikọ iroyin BBC News Yoruba sọrọ ko fẹ ki a gba ohun wọn silẹ, alaye wọn ni wi pe ọkan lara awọn aṣoju ẹgbẹ awakọ naa, Alhaji Mukaila Lamidi ti ọpọlọpọ eeyan mọ si 'Auxiliary' lo ko awọn ọmọ ẹgbẹ kan lẹhin lati tọpinpin aṣoju igun mii ninu ẹgbẹ naa, ti wọn pe inagijẹ rẹ ni 'Ajanaku' wa si ile rẹ to n bẹ l'agbegbe naa.

Koko nnkan ti o ṣe okunfa ede aiyede lasiko abẹwo naa ko han si ẹnikẹni, eyii lo si mu ibẹrubojo de ba awọn olugbe adugbo naa, paapaa julo lasiko ti wọn ṣe akiyesi wi pe wọn fi ipa gbe 'Ajanaku' lọ si ile itura 'Auxiliary' to n bẹ ni agbegbe Alakia nilu Ibadan, gẹgẹ bi awọn aladugbo ṣe sọ.Wọn fi idi ọrọ mulẹ wi pe lẹhin wakati diẹ ni Ajanaku pada si ile rẹ ni agbegbe naa. Wọn ni Auxiliary ko ko ohun ija wa, bẹẹ si ni wọn ko yinbọn ni asiko abẹwo naa, ṣugbọn ifarahan wọn lo mu ki awọn olugbe Ẹgbẹda sa kijokijo lasiko naa.Ikọ BBC News Yoruba kan si olu ileeṣẹ ajọ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ lori ọrọ naa, wọn ṣe alaye wi pe ahesọ ọrọ lasan ni wi pe iro ibọn ati awọn ohun ijagun oloro ni awọn ẹgbẹ awakọ fi le awọn olugbe Ẹgbẹda lopin ọsẹ.

EFCC: Àwọn ọba aládé àti olóṣèlú ṣé àpapín owó ìrànwọ́ N2bn ní Kwara

Lasiko to fesi lori ẹsun naa, Alhaji Mukaila Lamidi ti ọpọlọpọ eeyan mọ si 'Auxiliary' ṣe alaye wi pe igbiyanju lati ba oun lorukọ jẹ ni iroyin ẹlẹjẹ naa.O tẹsiwaju wi pe awọn ọta itẹsiwaju ti n lepa lati mu ki oun padanu oju rere gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde.Lẹhin ọjọ diẹ ti wọn bura wọle fun Ṣeyi Makinde gẹgẹ bii gomina ipinẹ Ọyọ ni o fi ofin de awọn ẹgbẹ awakọ, ti o si paṣẹ wi pe ki wọn kuro ni gbogbo ibudokọ ati awọn ikorita ti wọn ti n gba owo.Ọga agba ẹgbẹ awakọ, labẹ aburada NURTW, Alhaji Najeem Usman-Yasin ti ba gomina ipinlẹ Ọyọ ṣe ipade bonkẹlẹ lori ọrọ naa, ṣugbọn titi di asiko yii, aṣẹ naa ṣi duro digbi.

Awọn Iroyin mii ti ẹ le nifẹ si

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKayeefi: Facebook ni Wolii Arole Jesu fi tàn an wọ agbo, orí rẹ̀ ni wọ́n fi s'owó