Mo ti kó kúrò nílé Olu Jacobs rí lẹ́ẹ̀mejì- Joke Silver
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Joke Silva: Olu, ó tó gẹ́ pẹ̀lú obìnrin yìí níkan tó ń ba ẹ ṣeré ìfẹ́ nínú sinimá!

Iṣoro pọ ninu igbeyawo mi ṣugbọn kò si ibi ti mo n lọ -Joke Silva

Iriri kọja ẹgbẹ abẹwu, ohun ti agbalagba ri lori ijokoo, Yoruba ni oju ọmọde ko lee too laelae lori iduro.

Agbaọjẹ oṣere, Joke Silva aya Gbajugbaja oṣere Olu Jacob ba BBC Yoruba lalejo ni olu ile iṣẹ wa.

Nibẹ ni ogbontarigi oṣere naa ti sọrọ lori ẹsun ifipabanilopọ ti Busola Dakolo fi kan Biodun Fatoyinbo to n dari ijọ COZA.

Joke Silva sọrọ lori igbeyawo oun ati Olu Jacob pẹlu imọran fawọn ọdọ ninu igbeyawo to fi ni lọkan balẹ.

Ogbontarigi oṣere-binrin yii ṣalaye idi ti oun fi n jẹ Joke Silva dipo Jacob orukọ ọkọ rẹ.

Bakan naa lo sọrọ lori bi o ṣe n ri lara oun ti ọkọ rẹ ba n ba obinrin mii ṣere ifẹ lori sinima.