Kollington vs Barrister: Ọ̀rẹ́ ni èmí àti Barrister kó tó jáde láyé

Kollington vs Barrister: Ọ̀rẹ́ ni èmí àti Barrister kó tó jáde láyé

Ọmọ ni Wasiu Ayinde Marshall jẹ́ si mi -Kollington.

Alhaji Ayinla Kollington to je agba oje olorin Fuji ni Naijiria gba BBC lalejo nile won fun iforowanilenuwo.

Baba kebe n kwara dahun ibeere nla to n fa ariyanjiyan lagboole Fuji lori eni to da ere Fuji sile.

Oríṣun àwòrán, OTHERS

O ni ere Fuji ti wa saaju ki oun ati Ayinde Barrister to bere orin kiko rara.

O ni oro apara lasan ni pe oun tabi Barrister ni awon jo da fuji sile.

Baba Alatika be gbogbo olorin Fuji lati jebure ki won fowo wonu.

O fi Olorun ati Anobi Muhomo be gbogbo olorin fuji ti won je kikida musulumi pe ki won dupe ti won.

Aajo aje ni eebu ti emi ati oloogbe Ayinde Barrister fi n bu ara ninu ariyanjiyan wa ninu orin fuji.

Koda aw'on Baba nla wa ninu ise orin gan an korin bu ara won ki onikaluku le ta oja tire.

Kollington ni ko le se ki ija ma wa laarin awon eniyan laye.

O gba imoran pe ti ija ba ti de ki onikaluku pari e ni alaafia fi le joba ni ile aye.