Jiti Ogunye: Ẹgbẹ Musulumi Sunni ni ijọba Naijiria lọwọlọwọ!

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán O ye ki ijoba fun won ni ohun ti won n beere fun to ba wa ni abe ofin

Agbẹjọro ati onimọ nipa eto ofin, Jiti Ogunye ti ni kii ṣe gbogbo agbara ti ijọba ni lo yẹ ki o ma a lo lori awọn ara ilu.

Ogunye sọ eyi lasiko ti o n fesi si bi ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe gbe ẹsẹ le iwọde lati ọdọ awọn ẹgbẹ Shia (IMN) to n se alatilẹyin fun adari wọn, El-Zakzakky to wa ni atimọle ijọba.

O ni ko bojumu bi ijọba ṣe sọ wọn da ẹgbẹ agbesunmọmi labẹ ofin 'Anti-terrorism Act' to fi ofin de ki eniyan ma a hu iwa ipa ni awujọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸ̀mí sùn níbi ìkọlù Shiite àti ọlọ́pàá

Agbẹjọro ati onimọ nipa eto ofin naa ni gbogbo ọmọ Naijiria lo ni aṣẹ ni abẹ ofin lati jọsin bi o ṣe wu wọn.

Bakan naa ni o fikun un wi pe o dabi ẹni pe ijọba n lo ọrọ El-Zakzakky lati ja ija ẹsin, nitori ẹgbẹ musulumi Sunni ni awọn to wa ni ijọba lọwọlọwọ.

Ogunye ni ijọba Naijiria n ba orukọ Naijiria jẹ nitori bẹẹ ni ijọba ṣe sọ ẹgbẹ IPOB to n beere fun orilẹ-ede ara re kuro lara Naijiria ni ẹgbẹ agbẹsunmọni,

Ni eyi ti Jiti ni ko pada so eso rere.

Agbẹjọrọ naa wa parọwa si ijọba lati jawọ nipa lilo agbara wọn laitọ, ti o si kesi awọn ara ilu naa lati ma a ṣe ifẹhọnu wọn ni ọna to ba ofin mu, ti ko si ni la ẹmi lọ.

Jiti Ogunye fesun kan pe ijọba Buhari gan an ni o n huwa bii agbẹsunmọni nitori awọn ṣoja pa awọn ọmọ ẹgbẹ Shia to to 360 ni ọdun 2015 gege bi oun se gbo

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJoke Silva: Olu, ó tó gẹ́ pẹ̀lú obìnrin yìí níkan tó ń ba ẹ ṣeré ìfẹ́ nínú sinimá