Ministerial List: Mo setan lati yan ise fun awon minista mi- Aare Buhari

Buhari Image copyright @Presidency
Àkọlé àwòrán Aare Muhammedu Buhari ti seatn lati yan ise fun awon minisita tuntun

Aare orile-ede Naijiria Muhammedu Buhari ti dupe lowo awon omo ile igbimo asofin Naijiria lori titete pari iforowanilenuwo fun awon minisita ti won fi sowo si won

Awon omo ile igbimo asofin agba lo ojo ise marun gbako lati ri si iforowanilenuwo awon minisita, eyi ti won ti bere lati ojo ojoru, ojo kerinlelogun osu keje si ojo isegun ogbon ojo osu keje lati pari ioforwanilenuwo fun awon minisita metalelogoji ti won ti fi oruko won ranse si ile asofin lojo ketaleogun osu keje.

Aare Buhari ni oun ni igbagbo lati le fun won ni ile ise ti won a ti sise laipe.

'' Modupe lowo gbogbo awon omo ile igbimo asofin agba ti won fi ara ji lati sise lori awon minisita to won ko si fi fale rara''

''Awon omo Naijiria n fe ri abajade ise ti ijoba n se, pelu awon eniyan to wa ninu minisita.

Mo nigbagbo pe ise ijoba yoo mu ere dani.

N o yan ise won fun won ni kete ti a ba ti se ifilole awon alase leyin ibura wole won gege bi aare se so ninu atejade kan lale ojo Isegun.

Opo awon omo Naijiria lo n fokan si i pe aare yoo se ifilole awon omo igbimo re lojo Isegun lasiko ipade awon alase ijoba.

Ninu awon minisita metalelogoji ti aare yan, obinrin meje pere lo wa ninu won.

Awon mejila ni yoo je agba omo igbimo nitori pe igbakeji won ree sugbon ko si eni omo odun marundinlogoji kankan ninu won.

Hadi Sirika, Chris Ngege, Rotimi Amaechi, Babatunde Fashola, Ogbonnaye Onu, Lai Mohammed Adamu Adamu, Geofrey Onyema, Zinab Ahmed ati Osagie Ehimere ni awon minisita to ba aare sise ni saa to koja