Shiite: Kò ní sí ìwọ́de mọ́ yíká Nàíjíríà láti bu ọ̀wọ̀ fáwọ̀n èèyàn tó dá sí wa

Awọn ọmọ ẹgbẹ Shiite n sewọde Image copyright Empics

Ẹgbẹ Shiite ti kede pe oun ti wọgile awọn iwọde gbogbo loju popo ilu Abuja, eyi to ni se pẹlu itusilẹ olori wọn, Ibrahim El-ZakZaky.

Igbesẹ yii lo waye lẹyin wakati mẹrinlelogun ti ọga agba ọlọpa nilẹ yii, Mohammed Adamu kede ijọba ti fofin de ẹgbẹ Shiite.

Atẹjade kan ti ẹgbẹ Shiite fisita sisọ loju rẹ pe, oun gbe igbesẹ naa lọna ati faaye gba iwadi nipa isoro to n koju wọn, paapa ẹjọ tawọn agbẹjọro awọn gbe ls sile ẹjọ eyi to da lori bijọba apapọ se kede pe oun ti fi ofin de ẹgbẹ ẹlẹsin musulumi naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIya Adura Esther Ajayi sọ àṣírí owó rẹ̀ tó fi ń ṣàánú

"A gbe igbesẹ naa pẹlu igbagbọ nla ati ọwọ taani fun awọn eeyan iyi ati ẹlẹgbẹjẹgbẹ ti wọn da si ọrọ yii, a si lero pe wọn yoo wa ọna lati yanju awọn aawọ to wa nilẹ nitubi n nubi, paapa lori bi wsn se ti asaaju wa mọle lati bii ọdun mẹrin sẹyin."

"Ti ifẹhonu han kankan ba si waye nibikibi lorilẹede yii, a jẹ pe atẹjade yii ko tii tẹ awọn to wa nibẹ lọwọ ni, tabi pe wọn si ọrọ yii gbọ abi awọn agbofinro lo wa nidi isẹlẹ naa, gẹgẹ bi wsn ti n se lati latẹyinwa lati ta ẹrẹ si asọ ala wa, lọna ati mu kawọn eeyan maa fi oju arufin wo wa, dipo oju awọn eeyan ti wọn n fi iya jẹ lati ọdun 2015."

Image copyright @enso_uzor

Atẹjade naa tun wa n dupẹ pupọ lọwọ awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ajafẹtọ ẹni nilẹ yii ati loke okun, ati awọn ajafẹtọ ẹni lori ikanni ayelujara, fun bi wọn se gbe awọn iroyin to nii se pẹlu iwọde wọn sita lasiko ijagudu fun idajọ ododo naa.

Ẹgbẹ Shiite tun tẹnumọ ipinnu rẹ lati wa ọna abayọ miran lati yanju isoro ọlọjọ pipẹ to n koju wọn ọhun, ti wọn si tun n beere fun itusilẹ asaaju wọn, iyawo rẹ ati ọpọ ọmọ ẹgbẹ Shiite miran to wa ni ahamọ, ti wọn si fi ẹtọ si ominira dun wọn lati ọdun 2015.