Kiiling of Nigerians: Ijọba Nàìjíría fá orílẹ̀-èdè South Africa létí

Awon to n wode Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Abike Dabiri pè fún ìwádìí tó péye lórí gbogbo àwọn tí wan ti pa kí wan si fi ẹni ti igbá ba ṣí mọ lóri jófin

Ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí kìlọ̀ fún South Africa, pé òun kò ní faramọ pípà ọmọ Nàìjíríà ní ìpakúpa, àti ni àìni ìdí tó n wáye lórílẹ̀-èdè South Africa lójoojúmọ mọ, nítorí pé oni sùùrú Nàìjíríà ti gbẹ lórí ọ̀rọ̀ náà

Adarí àgbà àjọ tó ń ri sí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ní òkè òkun (NIDCOM) Abike Dabiri, tó fi ìkìlọ̀ náà sọwọ́ ní ìlú Abuja ní ọ̀sán òní ọjọ́ru, sàlàyé pé ìwà ìpani ni yiìí ti kọjá afaradà fún ọmọ Naàìjírìà.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSunday Igboho: Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọ̀n bàbá wa
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionRevolutionNow: Ẹ̀rù ò bàwá, a ṣetan láti wà ní àtì mọ́lé- olùfẹ̀hónúhàn

Lásìkò tó ń ba àwọn akọroyìn sọ̀rọ̀, ìwà pípà àwọn ọmọ Naikjiria tó n fi ojojúmọ peléke síi ní South Africa tí de ori góngó báyìí, o fí kún pé tí ọmọ Naijírì kan ba tú kú ní South Africa, gbogbo ọmọ South Africa to ba wà ní Nàìjírìa náà kò ni farare lọ

O sàlàyé pé àwọn ọmọ Nàìjíríà méjìdínláàdọ́fà ní wan ti pa ni South Africa láti ọdún 2016, o fi kún un pé láàrin 2016 si àsìkò yìí ànìyàn méjìdínláàdọ́rùn ni wọ́n tún pa

Ó pè fún ìwádìí tó péye lórí gbogbo àwọn tí wan ti pa kí wan si fi ẹni ti igbá ba ṣí mọ lóri jófin

Ẹ̀wẹ̀, ọ̀gá NIDCOM ní ọ̀rọ̀ náà kan òhun lóminú pé àwọn ọmọ Nàìjíríà míràn ló ṣe okùnfa ìkú akẹgbẹ́ wọ́n nítoripé nígbà míràn àwọn ọmọ Naàìjírà ló lọ́wọ́ kún ọmọ Nàìjíríà.

O tún pè fún ìwádìí tó péye lóri ikú to pa ìgbákeji àdári àgbà ilé iọ̀ẹ́ tó ń ri sí ètò adójutofo ní Nàìjíríà Elizabeth Ndubuisi- Chukwu.