2019 Flood Alert: Àṣírí ọ̀nà tí ẹ le gbà dèna omí yale rèé.

Agbara omi
Àkọlé àwòrán Àwọn ọ̀nà ti ẹ lè gbà kojú omí yale àgbára ya sọọbù

Omí yale àgbàrá ya sọ́ọ̀bù jẹ́ ìsòrò kan gbòógí tó máa n ba ilé jẹ, ba ọ̀nà jẹ, ǹkan ìní yóò sòfò kọ́dà ẹmi a máa báa lọ ni ọ̀pọ̀ ìgbà.

Ní ọdún yìí àjọ tó ń ri sí bí ojú ọjọ ṣe ri ti kìlọ pé àwọn ìpínlẹ̀ marun un ní gúúsù ìwọ̀-oorù Nàìjíríà Lagos, Ogun, Ondo, Oyo àti Osun yóò kojú ẹkún omi yale àgbàrá sọọbù.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKayeefi: Facebook ni Wolii Arole Jesu fi tàn an wọ agbo, orí rẹ̀ ni wọ́n fi s'owó

Nítorí ìdí èyí ni BBC Yorùbá ṣe sàlàyé àwọn ọ̀nà ti e lè gbà láti dènà ìṣòro omíyale àgbàrá ya sọọbu.

Kíni àwọn ìgbẹ́sẹ̀ láti dènà omíyale àgbàrá ya sọ́ọ́bù

Ó ṣe pàtàkì láti mọ pé kò yẹ láti kọ́le si etí ibí ti omí odò ń gbà kọjá tabi kọle si ojú àgbàrá: O wá ṣeéṣe ki ẹlòmiran ti kọ́le si ètí omí, ọ̀nà abáyọ míràn tún ní pé, lásìkò ọ̀gbẹlẹ̀, o ṣe pàtàkì láti mọ ọgbà yii ilé náà ka, bákan náa ní kí a gbìyànjú láti gbin igi ti yóò dúro bi araba lati dí agbàrá lọ́wọ́, láti ma wọle.

O ṣe pàtàkì láti máa dágunla si ìkéde àjọ tó n ri sí bí ojú ọjọ́ yóò ṣe rí: Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ní àwọn àjọ yìí máa ń kéde bí ojú ojọ́ yóò ṣe ri, òjò ti yóò fa ọmí yale, nígbà ti irú ìpè yìí bá wáye kò yẹ ki ará ìlú keti ọ̀gbọ́in síi, ó ṣe pàtàkì láti maa gbọ rẹdíò, tẹlẹfisọn àti kika ìwé ìròyìn ní gbogbo ìgbà láti mọ nípa àwọn apá ibi ti amíyale yóò ti wáye.

Gẹ́gẹ́ bi ọlọ́dani o ti dídandan láti dẹ́kun jíju ìke àti ọ̀rá sí ojú àgbàrá: Ní ọ̀pọ̀ ìgbà àwọn ìgbòkegbòdò ará ìlú náà maa ń dẹ́kun omiyalé àgbàrá ya sọ́ọ́bù, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ti wọ́n ba ti gbọ́ kíkù òjò ní wọ́n ti lọ da gbogbo ìdòtí ilé wọ́n sí ojú ibi ti ó yẹ kí àgbàrá gbà, èyí jẹ ọkan lára ǹkan ti ó ń fa ẹkún omi, bákan náà o ye ki ará àdúgbò maa kóra jọpọ̀ láti ṣe ìtóju ojú àgbàrá

Ìjọba ní láti gbé ìgbésẹ̀ lóri bí ojú ọjọ sé ń yí: Ọ̀rọ̀ àyí padà ojú ọjọ́ jẹ ǹkan pàtàki tí gbogbo ìjọba gbe lọ́wọ́ ní àgbàyé, èyí jẹ ǹkan ti o yẹ ki ọlọdani náà mọ, àyípada ojú ọjọ́ ló faa ti omi fi kú kọjá ibi tó yẹ, nítori ìdí èyí ọ̀rọ̀ náà kìí ṣe ti ìjọba nìkan bíkoṣe pe àti ará ìlú àtí ìjọba ló yẹ ko saapa láti dẹkun omiyale

Ìjọba gbọdọ sẹ àtúnṣe àwọn ojú àgbàrá àti ibi ti omí to ba ń jade lati ojúle kọ̀ọ̀kan yóò maa dari si: Ọ̀pọ̀ àwọn awọn orilẹ̀-èdè lo ti ṣe àwọn ètò yìí nígbà ti wọ́n bá n ṣètò àdúgbò síbẹ, ìjọba orilẹ̀-èdè, pàápàá jùlọ ìjọba ìpínlẹ̀ kìí ṣe àwọn ètò yìí, bí ìjọba bá le ṣe àdínkù yóò ba ẹkun omi yale àgbàrá ya sọọbu.