Hajj: Ǹjẹ́ o mọ pàtàkì Ọjọ́ Àràfá fún àwọn mùsùlùmí?

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn musulumi ma n ya Ọjọ Arafa sọtọ lati fi gba adura kaakiri agbaye pẹlu àwọn ti won rin irinajo lo si ilẹ Mecca.

Ọjọ Arafa bọ si Ọjọ Kẹsan ti awọn musulumi n pe ni Dhul-Hajjah, to jẹ ọjọ keji Hajj.

Ọjọ nla ni Ọjọ yii jẹ ninu irinajo awọn musulumi lọ si ilu Mecca, ilẹ mimọ, to si jẹ ọkan ninu awọn ọjọ to se pataki si wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption''Ọjà ẹran àgbò kò yá bí ti ọdún tó lọ''

Ti oorun ba ti jade ni ọjọ yii, ni awọn musulumi ti wọn lo bi ilẹ mimọ yoo bẹrẹ irinajo lọ si Oke Arafa to wa ni Mecca.

Ki ni idi ti Ọjọ Arafa fi se pataki si awọn musulumi?

  • Ọjọ Arafa ni ọjọ to kangun si ọjọ Eid-al-Adha, iyẹn Ọjọ Ileya, eleyii ti wọn ma n se ni aadọrin ọjọ lẹyin ọdun Ramadan.
  • Ọjọ yii jẹ ọjọ ti ẹsin Musulumi gba ibukun ati ire lẹnu Allah gẹgẹ bi ẹsẹ Iwe Mimọ Quran ti kọ silẹ.
  • Ọjo Arafa ni Ọjọ keji Hajj ti awọn musulumi jakejado agbaye to lọ si Mecca yoo gun oke aanu arafa to sun mọ Makkah.
  • Oke Arafah ni Ojisẹ Allah, Mohammed se ẹsiin ati iwaasu ikẹyin to fi ki wọn pe o digba kan naa.
  • Ni Ọjọ Arafa, awọn musulumi ti ko le e lọ si Mecca, ma n gba aawẹ ati adura, nigba ti awọn to lọ si oke Arafa yoo fi gbogbo ọjọ naa gba adura.
  • Ọjọ Arafa jẹ ọjọ ti awọn musulumi ya sọtọ patapata lati gba adura fun idariji ẹsẹ ti ọdun to kọja ati eleyii ti n bọ.