El-Zakzaky: Arúfin ni ijọba Muhammadu Buhari gan-an - Ladoja

Laodoja
Àkọlé àwòrán El-Zakzaky: Arúfin ni ijọba Buhari gan-an - Ladoja

Gomina tẹlẹri nipinlẹ Ọyọ, ti o tun jẹ Osi Olubadan ti ilẹ Ibadan, Oloye Rashidi Ladọja ti bẹnu atẹ lu ijọba apapọ lori ẹgbẹ Shiite, gẹgẹ o ti ṣe alaye wi pe ijọba apapọ gan an lo n ru ofin lori aṣẹ ti ile ẹjọ pa wi pe ki wọn da adari ẹgbẹ naa, El-Zakzakky silẹ.Ladọja sọ ọrọ naa nibi ipade awọn oniroyin ti o waye lọjọ Aiku ni ile rẹ to n bẹ ni agbegbe Bodija niluu Ibadan.