Atiku: Igun olùjẹ́jọ́ gan kò fèsì sí àṣìṣe ìṣirò tí ẹlẹ́rìí kan mẹ́nubà pé INEC ṣe

Atiku Abubakar Image copyright @atiku

Ẹgbẹ oselu PDP ati oludije rẹ fun ipo aarẹ to kọja, Atiku Abubakar ti kasẹ atotonu wọn nilẹ niwaju igbimọ to n gbọ ẹjọ ẹhonu to suyọ lẹyin ibo naa.

Nigba ti wọn n kalẹ alaye ẹhonu wọn ọhun nilẹ, wọn fẹsun kan pe wọn ja awọn lole ni nidi akojọpọ esi ibo aarẹ eyi to mu ki wọn fidi rẹmi ninu abajade esi ibo ọhun.

Ninu alaye wọn, eyi ti asaaju ikọ agbẹjọro to n soju igun mejeeji, agba amofin Livy Uzoukwu gbe siwaju igbimọ olugbẹjọ naa, o ni asise waye nidi isiro awọn esi ibo aarẹ ni ipinlẹ mọkanla.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bi igun olupẹjọ naa ti wi, awọn ipinlẹ mọkanla ọhun ti asise isiro esi ibo ti waye ni ipinlẹ Bauchi, Borno, Gombe, Jigawa, Kaduna, Kano, Katsina, Kebbi, Niger, Yobe ati Zamfara.

PDP ati Atiku ni, to ba jẹ pe wọn ka awọn esi ibo naa bo se yẹ ni, awọn ko ba fi ibo to to 222,332 na aarẹ Muhammadu Buhari, tii se alatako latinu ẹgbẹ oselu APC, ti wọn kede pe o jawe olubori.

Image copyright Presidency

Ikọ olujẹjọ ni bi akojọpọ esi ibo aarẹ naa ba lọ bo se yẹ ko lọ, apapọ esi ibo to yẹ ki ẹgbẹ oselu PDP ati oludije rẹ fun ibo aarẹ gba ni 9,426,082, eyi ti wọn lo tayọ apapọ ibo Buhari ati APC tii se 9, 203,750.

Wọn wa kadi ọrọ wọn nilẹ pe lasiko ti igun olujẹjọ gan n kadi ọrọ rẹ nilẹ, ko tako ẹri ti ọkan lara awọn ẹlẹri ti wọn ko wa siwaju igbimọ naa, tii se akọsẹmọsẹ olusiro gbe kalẹ, eyi to n tọkasi pe asise wa ninu esi ibo ti ajọ INEC kede.