SSANU, NASU yóò bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì lọ́jọ́ Ajé láti fa ìjọba létí

Ọgba ile ẹkọ kan Image copyright Getty Images

O da bi ẹni pe iṣẹkuṣẹ ni awọn oṣiṣẹ fasiti yoo fi ṣẹ orilẹede Naijiria lọwọ ni ọjọ aje ọjọ kọkandinlogun oṣu kẹjọ ọdun 2019 pẹlu bi wọn ni kede pe awọn yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi jakejado orilẹede Naijiria.

Ki ni idi gan ti wọn fẹ fi gunle iyanṣẹlodi yii? Ẹyin naa beere?

Ohun ti aarẹ ẹgbẹ awọn agbaagba oṣiṣẹ fasiti lorilẹede Naijiria, SSANU, Kọmureedi Samson Ugwoke sọ ni peawọn owo ajẹmọnu kan ti ijsba jẹ wọn, pẹlu bi ijọba ṣe le awọn oṣiṣẹ ileewe alakọbẹrẹ ati girama to wa labẹ iṣakoso awọn fasiti to fi mọ awọn ẹhonu pẹ-pẹ-pẹ miran to nii ṣe pẹlu bi nnkan ṣe n lọ si ni ẹka ileewe giga fasiti lorilẹede Naijiria ni o n sun awọn kan ogiri ti wọn fẹ fi gun le iyanṣẹlodi yii.

Gẹgẹ bi o si tun ṣe tẹsiwaju lati sọ,ọjọ aje ni iyanṣẹlodi naa yoo bẹrẹ lẹyẹ-o-ṣọka.

O ni gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ SSANU ati NASU lo ti wa ni imurasilẹ fun iyanṣẹlodi naa eleyi ti wọn ni awọn yoo fi naa tan bi owo pẹlu ijọba.

Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, ọjọ marun ni iyanṣẹlodi naa yoo fi waye nitori wọn fẹ fi fa ijọba leti ni lẹyin ti wọn ti fun ijọba ni gbede ọjọ mẹrinla lori ibeere wọn naa ṣaaju asiko yii eleyi to ni ijọba kọ eti ọgbin si.