Lateef Adedimeji: Owó wa kò bá máa jóná ṣùgbọ́n aàyè ọpẹ́ ń yọ fún wa

Lateef Adedimeji: Owó wa kò bá máa jóná ṣùgbọ́n aàyè ọpẹ́ ń yọ fún wa

Orọ aṣiwere ló n yatọ, bakan naa ni ọrọ ọlọgbọn awọn oṣere yii ri lori wahala to rọ mọ ṣiṣe sinima.

Idi iṣẹ ẹni ni a ti n mọni lọlẹ ni awọn agba maa n wi nilẹ Yoruba.

Awọn agba ọjẹ oṣere bii Jaiye Kuti, Fathia Williams, Abdulateef Adedimeji sọrọ ni kikun lori ipenija iṣẹ sinima ṣiṣe ni Naijiria.

Gbajugbaja oṣere Yoruba, Jaiye Kuti sọrọ lori pataki iṣẹ ti fiimu kọọkan n jẹ ni eyi to gba iṣẹ ọpọlọ.

Bakan naa ni wọn jọ mẹnuba inawo inu gbigbe fiimu tuntun sita.

Ni eyi ti ogbontarigi oṣere Fathia Williams fi ni o tẹ oun lọrun lati jẹ oṣere ju olootu lọ nitori ko rọrun lati ko oriṣiriṣi ori jọ ninu sinima.

Thomas Odia to jẹ oludari fiimu Eru Ajọ tuntun ti wọn n ya lọwọ ni Ibadan naa sọrọ lori ohun oju ri.

O ni iṣẹ oludari paapaa kii ṣe kekere nitori ero oṣere ati oludari maa n yatọ ni ọpọ igba ni.