AfroBasketWomen: Buhari kí D'Tigress lẹ́yìn tí wọ́n ṣíná ìyà fún Senegal gba ife

D'Tigress Image copyright Twitter/FIBA
Àkọlé àwòrán La ba gbe ife ẹyẹ lọ kuro ni Senegal!

Aarẹ Muhammadu Buhari ti gboriyin fun awọn ikọ agbabọọlu alapẹrẹ Naijiria, D'Tigress pe wọn ku iṣẹ.

Lọjọ Aiku, ọjọ kejidinlogun ni awọn agbabọọlu obinrin ọmọ Naijiria yii fakọyọ ti wọn tun gbe ife ẹyẹ Afrobasket lọ.

Awọn naa ni wọn gba a lọdun 2017 ti wọn gbogo wale fun Naijiria.

60 -55 ni wọn fi fagbahan ikọ Senegal to gbalejo idije naa nibi ti o le ni ẹgbẹrun mẹẹdogun oluworan ti kopa.

Aare Muhammadu Buhari to n tukọ orilẹ-ede Naijiria naa ti gboṣuba rabandẹ fawọn olu ọmọ wọnyii pe wọn gba ife ẹyẹ naa lẹẹkan sii.

Otis Hughley to je akọnimọọgba ikọ awọn obinrin yii fi idunnu rẹ han lasiko to n ba BBC sọrọ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán A tun bori ni 2019 - Naijiria

O ni inu oun dun pupọ pe idije bọọlu alapẹrẹ ti ni idagbasoke to yẹ laisko yii.

O tun gboriyin fawọn agbabọọlu obinrin ti Naijiria ti o n kọ pe pe wọn fakọyọ daadaa.

Ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo ni iṣẹ takuntakun ni awọn obinrin n ṣe ninu ogo ere idaraya Naijiria lasiko yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWolii Arole