A mọ̀ pé ó léwu; ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ ṣe pàtàkì -Òbí ní Gbẹ̀rẹ̀fù Badagry
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Badagry: Erékùṣù tí àwọn ọmọdé ti ń wọ odò ńlá láti lọ sílé ìwé

Ko si ẹwu idaabobo fawọn ọmọ wa lori odo nla yii.

Ibi ori da ni si laa gbe ni igbagbọ iran Yoruba.

Awọn eniyan erekuṣu Gbẹ̀rẹ̀fù nitosi Badagry ni ipinlẹ Eko ni wọn n gbe ni aarin gbungbun odo nla.

Wọn ba BBC Yoruba sọrọ lori igbe aye wọn ati ipenija ti oju wọn n ri nitori ibi ti ori da wọn si ti wọn n gbe yii.

Olorunwa Ariwayo, Jumoke Hassan, Isaiah Abass atawọn miran ṣalaye fun BBC Yoruba bi awọn ọmọ erekuṣu yii ṣe maa n gba ori omi nla Badagry yii lọ sile iwe lojoojumọ.

Wọn mẹnuba ewu to rọ mọ irinajo yii nitori ko si ẹwu idaabobo rara ṣugbọn pataki ẹkọ fawọn ọmọ wọn lo mu wọn moju kuro.

Awọn obi ati alagbatọ agbegbe yii mẹnuba bi ẹru ṣe maa n ba wọn nigba gbogbo ti awọn ọmọ wọn ba n lọ sile iwe.

Tabi ti awọn iyawo wọn ba n rọbi, nitori ko si ile iwe, ile iwosan tabi ina monamona ni erekusu yii