Àwọn tó ń sanwó orí ti rúgọ́gọ́ sí lábẹ́ ìjọba Buhari

Fowler

Oríṣun àwòrán, Babatundeofficial

Àkọlé àwòrán,

Àwọn tó ń sanwó orí ti rúgọ́gọ́ sí lábẹ́ ìjọba Buhari

Abba Kyari ko fi Fowler si abẹ iwadii kankan - Garba Sheu.

Ilé isẹ́ ààrẹ ní ọgá àgbà ilé iṣẹ́ tó n ri sí owó orí lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Babatunde Fowler ko si lábẹ́ ìwádìí kankan lódi si bi àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn kan ṣe ń tan kiri.

Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì sí ààrẹ Muhammadu Buhari lóri ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ Garba Sheu, sàlàyé ọ̀rọ̀ náà nínú àtẹjáde kan to fi síta.

O ní lẹ́ta tí olórí òṣìṣẹ́ ilé ilé ìjọba Abba Kyari kọ tó sì ń da awuyewuye náà silẹ̀ kàn wà fún ọ̀nà láti pe àkíyèsí ilé iṣẹ́ náà si ìlànà òdì ti wọ́n ń gba láti gba owó orí ni lọ́ọ́lọ́ yìí ni.

Àkọlé àwòrán,

Fowler kò sí lábẹ́ ìwádìí kankan-Garba Sheu

Garba fi kún un pe àpẹẹrẹ òhun ọtun ni ọ̀rọ ti ààrẹ só lásìkò ìpàgọ àwọn mínísítà túntún àti àwọn akọwé ilé iṣẹ́ ìjọba.

Eto naa waye níbi ti igbákeji ààrẹ Yemi Osinbajo ti sọ̀rọ lọ́ri àfojusùn ìjọba lóri gbigba owó ori wọlẹ́ láì wo owó ìná ojoojúmọ́ àti gbogbo owó tí ijọba yóò lò fún àwọn iṣẹ́ àkànse.

O ni ìgbákeji ààré fi kún un pé bi ǹkan bá ń lọ bẹ́ẹ̀, wàhálà yóò súyọ ninu ètò ìsúná orílẹ̀-èdè yìí laipẹ.

Eyi to jẹ pe ti ìgbésẹ̀ tó tọ kò bá tètè wáyé láti fi òpin si ònà ti kò bá òfin mú nípa ṣíṣe ètò àfojusun owo ori tó n wọle le fi bi wahala.

Ẹ̀wẹ̀, Garba fi kún un pé, ìyé àwọn ẹni to ti tóójúbọ to sì ń san owó orí ti sún láti mílíọ̀nù mẹ́wàá sí ogun mílíọ̀nù ènìyàn pàápàá jùlọ lábẹ́ ìjọba ààrẹ Muhammadu Buhari.

Àkọlé fídíò,

Badagry: Erékùṣù tí àwọn ọmọde ti n wọ odo ńlá láti lọ sílé ìwé