Ẹni tí kò jẹ gbì kò lè kú gbì, eré ọmọdé ni EFCC ń ṣe - Ambode

Ambode Image copyright Ambode
Àkọlé àwòrán Gbogbo ètò ló tí n lọ láti ṣe ìwádìí ẹsún ti wọn fi kan Ambode, lẹ́yìn ti a tí gbsẹ̀ lé owó báǹkì láìpẹ́ yìí

Lẹyin ti awọn oṣiṣẹ EFCC atawọn ọdọ ilu Ẹpẹ gbena woju ara wọn lasiko ti wọn fẹ ṣe ayẹwo ile gomina ana ni ipinlẹ Eko, Akinwunmi Ambode, gomina ana naa ti sọrọ sita.

O ṣalaye pe wọn ko ri ohunkohun to lee fa họwuhọwu lẹyin ayẹwo wọn.

Ninu atẹjade kan to fi sita lẹyin ti awọn oṣiṣẹ EFCC naa gbọn ile rẹ to wa nilu Ẹpẹ ati Parkview ni Ikoyi yẹbẹyẹbẹ, Akinwunmi Ambọde ni wọn ko ba ẹbọ ni ile oun lẹyin ti wọn ṣe ayẹwo wọn tan.

Ambọde ni titi di bi a ṣe n sọrọ yii, ko si igba kan ti ajọ EFCC ba oun ni gbolohun lori ohunkohun yoo wu.

Ati pe nigbakugba ti wọn ba nilo oun, ko si giri, oun ṣetan lati jẹ wọn ni hoo.

O wa rọ awọn ololufẹ rẹ lati bu omi suuru mu ki wọn si gba alaafia laaye nitori gẹgẹ bi o ṣe sọ, 'ko si giri!'

EFCC ya bo ìlé Akinwumi Ambode

Àjọ tó gbogun ti ìwà àjẹbánu lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, EFCC ni iwadii lasan ni awọn n ṣe.

EFCC ní ilé gomina ìpínlẹ̀ Eko tẹ́lẹ̀rí, Akinwumi Ambode ti awọn lọ ni owúrọ òní jẹ́ ìtẹ̀síwájú ìwádìí àwon lóri ẹ̀sùn ìkówó jẹ tí wọ́n fi kàn-àn.

Gẹ́gẹ́ bi Tony Orilade tó jẹ agbẹnusọ EFCC ṣe sọ, ó ni kìí ṣe pe àwọn yabo ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ìròyìn tó ń lọ nígboro.

Ìwádìí lásàn ní à ṣe lọ sí ilé Ambode-EFCC

Nígbà ti akọròyìn BBC Yoruba bèèrè ìdí tí wọ́n fi wà ní ilé Ambode, Tony Orilade ní "báwọ ni à ó ṣe ya bo ilé Ambode, ǹjẹ́ ẹ mọ ǹkan ti yabo túmọ̀ sí? ó túmọ sí ìkọlù, láti já wọle, tàbí láti jale"

"Ìwádìí ń lọ lọ́wọ́ tí ẹ ò bá gbàgbé a fí àtẹ̀jáde kan síta laipẹ nígbà ti a lọ sí ilé ẹjọ láti gbéṣẹ̀ lé owó nilé ìfówópamọ mẹ́ta kan ti wọ́n lò láàrín inú oṣù kẹsan an ọdun 2018 sí osù karún un ọdún yìí nílu Eko."

Orilade ní ó pọ̀n dandan lati ṣe àbẹwò sí ilé ẹni ti wọ́n ba ń ṣe ìwádìí, ó jẹ ìtẹsíwájú ìwádìí àwọn ni.

Bákan náà ni ilé iṣẹ́ BBC bèrè pé ṣe wọn ti pe Akinwumi Ambode fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nùwò súgbọn ọgbẹ́ni Orilade ní Ambode mọ pé àwọn ń ṣe ìwádìí lọ́wọ́.