Ọlọ́pàá Germany ń wádìí àfurasí mẹ́rin nínú àwọn tó kọlu Ekweremadu ni Germany

Image copyright @Ekweremadu
Àkọlé àwòrán Emi ti dariji awọn to ju ẹyin lu mi ni Germany

Awọn ọmọ Naijiria kan foju Ekweremadu han eemọ ni GermanyIke Ekweremadu, igbákejì ààrẹ ilé aṣòfin àgbà tẹ́lẹ́ rí èèmọ̀ he nilùú Germany!.

Gẹgẹ bi iroyin ti a gbọ ṣe sọ, nṣe ni wọn fi iwe pe Sẹnetọ Ekweremadu si ibi eto nla kan ti awọn ọmọ ẹya Igbo to n gbe ni ilu Nuremberg gbe kalẹ.

Gẹgẹ bi ipe ti wọn pe e, oun ni yoo jẹ alejo pataki nibi eto naa nibi ti ohun gbogbo ti yipada ti wọn si n sọ ẹyin adiẹ mọ ọ.

Ko pẹ lẹyin iṣẹlẹ yii ni Senetọ Ike Ekweremadu ti raaye pada si Naijiria ti iroyin si n tan kiri pe o ti dariji awọn to gbena woju rẹ ni Germany.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni Nurnberg ni orilẹ-ede Germany ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC.

Wọn fi ye BBC laipẹ pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii ni kikun lori awọn afurasi mẹrin ti wọn n wadii lori iṣẹlẹ naa.

Oga agba Gabriels-Gorsolke to wa ni Fourth Office ni Nurnberg-Furth sọ fun BBC pe awọn n ṣe iwadii naa bii ti ọdaran ati pe ọwọ ofin yoo tẹ ẹni ti ade ba ṣi mọ lori.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJoe Igbokwe kò yẹ́ fún ipò ti wọ́n fún nípìnlẹ̀ Eko - Babatunde Gbadamosi

Kini ero awọn ọmọ Naijiria lori iṣẹlẹ Ike Ekweremadu yii?

Ọpọlọpọ nkan ni awọn ọmọ Naijiria ti n sọ lori ọrọ naa lori ayelujara lati igba to ti ṣẹlẹ.

Awọn ọmọ Naijiria kan gba pe ohun ti awọn ọmọ ẹya Igbo yii ṣe ni Germnay ku diẹ kaa to:

Awọn miran gba pe àṣìbí inú bíbí ni nitori Ekweremadu gbiyanju fun iran Igbo

Bẹẹ lawọn miran n beere ibeere nla pe ki ni Ekweremadu lọ ṣe ọdun iṣu fun ni Germany laduru ọdun iṣu to wa ni Naijiria

Bi awọn kan ṣe n bu igbakeji aarẹ ile igbimọ aṣofin Naijiria to kogba wọle pe ko si nkan ti Dauda rẹ da nigba ti o wa lori oye ati pe ikilọ leyi jẹ fawọn olori ti ko ba ṣe daadaa.

Opọlọpọ awọn eniyan ti kii ṣe iran Igbo ni iṣu ẹni lo ti ọwọ ẹni bọ epo ni ọrọ yii nitori ile kan naa ni gbogbo wọn ti wa ni ila oorun guusu Naijiria