COZA RAPE: Àjọ pẹntikọsita ní Nàìjíríà (PFN) sọ pé Biodun Fatoyinbo ní kò jẹ́ kí ìwádìí wọn parí

Fat Image copyright "others
Àkọlé àwòrán Iwadii ko le pari laijẹ pe Fatoyinbo yọju si PFN

Ajo awọn ẹni ẹmi ni Naijiria, eyi ti wọn n pé ni Pentecostal Fellowship of Nigeria (PFN), ti fi ọrọ lede pe awọn ko tii pari iwadii ti wọn n ṣe lori ẹsun ifipabanilopọ ti Busọla Dakolo fi kan Biọdun Fatoyinbo.

Ẹni ti o jẹ akọwe fun ẹgbẹ naa, Biṣọọbu Emma Isong lo fi ọrọ naa lede nigba ti o n ba ileeṣẹ BBC sọrọ nilu Eko lowurọ oni.

O sọ ninu ifọrọweró naa pe: olusọ agutan Biodun Fatoyinbo kọ lati yọju si ibi iwadii ti ajọ naa gbe kalẹ, bi o tilẹ jẹ pe, Busọla Dakolo ti yọju nitirẹ.

Image copyright Biodun Fatoyinbo/Facebook
Àkọlé àwòrán Fatoyinbo kọ̀ láti yọjú ni ìwáàdí ò ṣe parí

Awọn ajọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilé ìjọsìn pẹntikọsita ní Nàìjíríà (PFN) ti so pe iwadi ajọ naa si ẹsun ifipabanilopọ ti Busola Dakolo fi kan oludasilẹ ijọ Commonwealth of Zion Assembly (COZA), Pasitọ Biodun Fatoyinbo ko pari.

Image copyright Busola Dakolo/Facebook
Àkọlé àwòrán Ìwáàdí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ kò tíì parí

Ajọ PFN sọ pe iwadii naa ko pari nitori Pasitọ Fatoyinbo kọ lati yọju si igbimọ ẹlẹni marun-un to n ṣewadii ẹsun naa.

O te siwaju ninu ọrọ pe "iwadii ti ẹgbẹ PFN ṣe ko nii ṣe pelu iwadii ti awọn ọlọpaa."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCOZA: Ọpọ èrò ló jáde ṣe lòdì sí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ Fatoyinbo

Iwadii ẹgbe PFN lo waye nitori awuyewuye awọn eniyan ati awọn oniroyin lori ẹsun naa.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán A gbọ ẹjọ ẹnikan da...