Nigeria Custom: A kò tí ẹnu Bodè pa rárá- iléeṣẹ́ Aṣọ́bodè

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán A n ṣiṣẹ lori eto aabo ni agbegbe yii ni

Ileeṣẹ Aṣọbode Naijiria ni iroyin ofege ni pe awọn ti ẹnubode pa ni Sẹmẹ.

Ogbẹni Joseph Attah to jẹ agbẹnusọ fun ileeṣẹ aṣọbode Naijiria ni awọn ko ti bode Naijiria ati ti orilẹ-ede Benin Republic pa rara.

Attah ni awọn eniyan ni oore-ọfẹ lati wọle tabi jade lati Naijiria si Benin Republic.

O ni ko si ẹni to ni idi pataki lati wọle tabi jade ti ko ni le wọle laisi wahala.

Joseph Attah ni nitootọ ni sunkẹrẹ fakẹrẹ n wa lasiko yii ṣugbọn awọn ko figba kankan ti ẹnu bode naa pa.

Ṣaaju ki Attah to sọrọ jade ni iroyin kan ti n lọ kaakiri pe awọn aṣọbode ti ti ẹnubode pa ni Sẹmẹ.

Alhaji Zubair Mai Mala, ọkan lara awọn oniṣowo ni ẹkun yii ni nitootọ ni awọn aniyan ti n duna dura ni ẹnubode yii.

O ni tita rira ti n lọ pada ni ẹnubode bayii.

Ogbeni Attah ni iṣẹ akanṣẹ lori eto aabo ti wọn pe ni Ex-Swift Response ni o n lọ lọwọ ni agbegbe naa.

O ni igbesẹ yii ni lati daabo bo Naijiria kuro lọwọ awọn agbesunmọmi, igara ọlọṣa, awọn onifayaywọ ati awọn to n ko nkan ija oloro wọle.

O ni iṣe akanṣe yii jẹ ajọṣepọ pẹlu awọn agbofinro, awọn aṣọbode, awọn to n risi iwọle ati ijade awọn eniyan, atawọn oṣiṣẹ eleto aabo miran.

Ko sọrọ lori gbendeke asiko ti iṣẹ akanṣe yii yoo gba.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMama Rainbow: iṣẹ́ tíátà kò ta sánsán mọ́ bíi ti ayé àtijọ́