Súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ ló sún wa dé ìdí kẹ̀kẹ́ gígùn -Awa Bike
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Awa Bike: Kẹ̀kẹ́ tiwa wà fún eré ìdárayá àti díndín èéfín agbègbè kù

Kẹ̀kẹ́ wíwà máa ń fún ni lẹmi gigun -Awa Bike.

Lati ọdun alalumọle ni kẹkẹ wiwa ti wa ni ilẹ Yoruba koda ṣaaju ki mọto gigun to di kari aye yii.

Laye ode oni ni oju awọn eniyan tun ṣẹṣẹ n ṣí si wiwa kẹkẹ pada.

Ife oluwa Ogundipe lo lọ kawe gboye imọ ijinlẹ keji lorilẹ-ede Faranse, lo ba kiyesi pe ko wu oun lati fi kẹkẹ wiwa silẹ lẹyin ọdun kan ti o ti n wa a kiri.

Ifeoluwa ni kẹkẹ yii ni oun wa ni ojoojumọ ni ile iwe oun ni France ti o fi n din inawo rẹ ku lori mọto wiwọ.

O pada sọ ero rẹ lori kẹkẹ wiwa di iṣẹ ṣiṣe lẹyin to pada wa sile.

BBC fọrọ wa awọn ti wọn n gun kẹkẹ daadaa bii Akin Salami, Fadekemi Adeleye atawọn mii lẹnuwo lori pataki kẹkẹ wiwa lasiko yii.

Wọn ni kẹkẹ wiwa dara nitori pe o wa fun ere idaraya ati ara lile.

O maa n din eefin agbegbe kù fun ilera pipe.

O n jẹ ki a bori sunkẹrẹ; fàkẹrẹ ọkọ wiwọ ni eyi ti o maa n fi akoko ẹni ṣofo.