Àṣà àti èdè Yorùbá dùn púpọ̀, o ní ìtumọ̀ kíkún

Ṣé iwọ ti ri iru ọmọ bẹẹ ri?

Idagbasoke ede ati aṣa Yoruba lo jẹ BBC Yoruba logun kaakiri agbaye.

Eyi lo mu wa jade lọ beere irufẹ ọmọ ti Yoruba n pe ni olugbodi.

Olugbodi jẹ ọkan alara orukọ Amutọrunwa ti iran Yoruba maa n sọ ọmọ wọn.

Yatọ si orukọ Abisọ, Inagijẹ, Adape, Ẹsin, Iṣẹ idile ati bẹẹ bẹẹ lọ, orukọ amutọrunwa ni a n sọ ọmọ nipasẹ bi a ṣe bii ati irufẹ ipo to fi wa saye.

Iyalẹnu lo jẹ fun wa pé ọpọ ninu awọn ti a fi ọrọ wa lẹnu wo ko fi bẹẹ gba idahun iru ọmọ ti Olugbodi jẹ.

Ṣugbọn inu wa dun pe ibeere yii jẹ ki awọn eniyan gbero lati pada lọ sile lọ beere nipa olugbodi lọwọ awọn agbalagba ile wọn.

A n parọwa fun koowa lati fi ede Yoruba ati aṣa ọmọluwabi kọ ọmọ wa lati kekere.

Olugbodi ni ọmọ ti a bi to ni ika ọwọ mẹfa.

Ika ọwọ kẹfa yii ni awọn eeyan gba pe Ajé ni.

Ajé ni iranṣẹ owó. ọlà ati aṣeyọri ninu igbagbọ Yoruba.

Ọpọ igba ni ika kẹfa yii maa n ré danu bi ọmọ naa ba ṣe n dagba sii tabi ti wọn maa n gee kuro nile iwosan.

Igba miran awọn agba ile maa n so okun mọ ika rebete yii titi a si fi re sọnu.