Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ ọkùnrin kan tó pa ọ̀rẹ́ rẹ̀ nítorí N40 ní Kano

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Ṣe o yẹ ki ẹmi eeyan sọnu nitori ogoji naira pere?

Awọn ọlọpaa nipinlẹ Kano sọ fun BBC pe awọn ti sọ Zaharadeen si gbaga.

Abdullahi Haruna to jẹ ọga agba ọlọpaa to n ṣe iwadii ọrọ yii ni iwadii ṣi n lọ lọwọ nitori iyalẹnu lo jẹ fun gbogbo eeyan.

O ni ohun ti wọn gbọ ni pe Zaharadeen ya ọrẹ rẹ Farawa to ti di oloogbe bayii ni ogoji naira ti Farawa ko si ri san ni asiko to da fun Zaharadeen.

Zaharadeen ni nigba ti oun lọ sin gbese ogoji naira ti ọrẹ oun Farawa ya ni ija bẹ silẹ laarin awọn mejeeji.

O ni ninu ija yii ni ọrẹ oun ti ṣubu lulẹ ki ọrọ to di ranto ni agbegbe Warawa ni ipinlẹ Kano ni ariwa Naijiria.

Jamilu Sani to jẹ oju mi too nibi iṣẹlẹ naa ni Kano sọ fun akọroyin BBC, Mansur, pé gbogbo awọn joko sibi igbafẹ ti awọn si jọ n ṣere ni.

O ni nigba to ya ni Zaharadeen n beere owo rẹ ti Farawa si ni oun ko tii ni owo naa ni eyi to dija laarin awọn mejeeji.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDomestic Violence: Ìjà láàrin lọkọlaya sọ aya dèrò ọ̀run

Jamilu ni: Zaharadeen ko lo ohun ija kankan, ọwọ lasan ni awọn mejeeji fi jọ n ja lasiko yii ati pe lojiji ni o fun Farawa ni iṣẹ nikun ti iyẹn dẹ ṣubu lulẹ ti gbogbo awọn si sare sibẹ lati gbee dide ki wọn fopin si ija naa.

Jamilu ni lẹyin eyi ni awọn sare gbe Farawa lọ sile iwosan Wudil Hospital nibi ti wọn ti ni pe Farawa ti doloogbe.

O ni: O ṣi n ṣe gbogbo wa ni kayeefi titi di isinyi, ko tiẹ ye wa mọ ni adugbo Warawa yii, nitori laipẹ ni ọmọ kan pa iya rẹ ni eyi to ṣi n ya wa lẹnu.

Opọ iṣẹlẹ lo ti ṣẹlẹ nipinlẹ Kano ti awọn eniyan ti pa ara wọn lori owo tabi ohun ti ko to nkan rara.

Loṣu to kója ni ile ẹjọ giga ni Kano ni Adajọ Dije Aboki dajọ pe ki wọn pa Umar Yakubu nipa okun siso lẹyin to pa ọrẹ rẹ Ibrahim Adamu nitori pe wọn n jiyan lori ogun naira (N20:00) ti Umar ya Ibrahim.

Koda, loṣu meji ṣeyin ni ọkọ kan fi ọmọ odo lu iyawo rẹ pa nitori pe ko tete jẹ iṣẹ ti oun ran an.

Abdullahi Haruna ni ipinlẹ Kano yii naa lo gun Mujitapha Musa ọrẹ rẹ pa lẹyin ti wọn ni ariyanjiyan lori idije El Classico laarin Real Madrid ati Barcelona loṣu kẹta ọdun yii.

Agbẹnusọ awọn ọlọpaa sọ fun akọroyin BBC pe asiko ti to ki ijọba gbajumọ ọlọpaa agbegbe to maa ni oye iṣẹlẹ lori eto aabo agbegbe kọọkan ati ọna abayọ ki awọn iṣẹlẹ bayii to maa gba ẹbọ ni Naijiria.