Sept 11 bomb: Wọ́n mú ọjọ́ ìgbẹ́jọ́ agbésúnmọ́mí 9/11 tó ṣẹlẹ̀ l'Amẹrika

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Iyan ogun ọdun...

Yoruba bọ, wọn ni iyan ogun ọdun a maa gbona fẹlifẹli.

Lọjọ kọkanla, oṣu kẹsan an, ọdun 2001 ni ọfọ ṣe ni amerika ti ọpọlọpọ ẹmi sọnu sinu ado oloro to dahun latọwọ awọn agbesunmọmi.

Ọpọlọpọ ojo lo ti rọ ti ilẹ ti fi mu lori iṣẹlẹ yii ni Amerika ati ni agbaye lapapọ.

Bayii wọn ti fẹ bẹrẹ igbẹjọ Mohammed Sheikh Khalid ti wọn ni oun ni ọpọlọ to wa nidi awọn agbesunmọmi iṣẹlẹ ọhun.

Mohammed ati awọn mẹrin miran ni wọn maa ṣe igbẹjọ wọn papọ ni ileejọ awọn ọmọ ogun ile ni Guatanamo Bay bẹrẹ lati ọjọ kọkanla, oṣu kini, ọdun 2021.

Lọjọ kinni, oṣu kẹta, ọdun 2003 ni wọn muu.

Ọjọ kérinla, oṣu kerin, ọdun 1965 ni wọn bi Mohammed.

Ẹsun agbesunmọmi, iwa ibajẹ lasiko ogun, ati iku awọn eniyan to to ẹgbẹrun mẹta ni wọn fi kan wọn.

Igba akọkọ ni yii ti awọn maraarun maa foju han nile ẹjọ lẹyin iṣẹlẹ New York, Washington ati Pennsylvania.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ko si aṣegbe laye, aṣepamọ niakn lo wa.

Kete ti wọn ba ti ṣe igbejọ yii tan ni wọn maa ṣe idajọ to yẹ fun wọn.

Iku ni yoo gbẹyin awọn maraarun ti wọn ba ni wọn jẹbi awọn ẹsun wọnyii.

Lọdun 2003 ni ọwọ tẹ Khalid ni Pakistan ki wọn to wa gbe e lọ si Guantanamo ni Cuba nibi ti wọn ti fẹsun naa kan an.

Laarin ọdun 2002 si 2003 ni ọwọ tẹ awọn mẹrin to ku.

Ileeṣẹ Otẹlẹmuyẹ CIA ti fọrọ wa awọn mẹrin to ku naa lẹnuwo ki awọn ọmọ ogun Amerika to ko wọn.

Awọn naa ni Walid Bin Attash; Ramzi Bin Al-Shibh; Ammar Al-Baluchi ati Mustapha Al-Hawsawi.