Domestic Violence: Ǹkan mẹ́jọ tó máa kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ kí olólùfẹ́ méjì tó pa ara wọn

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Ija kò dọlà, orúkọ lo n sọ ni

Ọpọlọpọ iṣẹlẹ lo maa n bi ija ati aigbọra-ẹni ye laarin ololufẹ meji.

O din diẹ ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn obinrin kaakiri agbaye ti wọn n doloogbe lati ọwọ ololufẹ wọn ti wọn n fẹ lọwọ tabi ti wọn ti fẹ sẹyin lọdun 2017.

Omowe Jane Monckton Smith to jẹ onimọ ijinlẹ nipa iwa ẹda lo ṣẹṣẹ fi abajade iwadii to ṣe sita lori iwa ipa laarin ololufẹ.

Ọmọ Biritiko to n kọni nipa iwa ọdaran yii sọ nipa ihuwasi awọn ti wọn ni ẹmi ati pa ololufẹ wọn hande.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDomestic Violence: Ìjà láàrin lọkọlaya sọ aya dèrò ọ̀run

Omowe Smith ni ẹni to ba ti fẹran lati maa jẹ gaba ninu ibaṣepọ ololufẹ meji lee ṣe iku pa ẹnikeji rẹ nijọ ti iyẹn ba kọ.

O ni ida ọgọrin ninu ọgọrun un awọn ti ololufẹ wọn n pa ti maa n fura tẹlẹ ṣaaju ki wọn to pa wọn.

Lẹyin ọpọlọpọ iṣẹ iwadii yii lo mu abajade ihuwasi mẹjọ wọnyii jade to yẹ ki onikaluku woye daadaa.

Igbesẹ mẹjọ to hande ninu ipaniyan mejilelaadọrin o le ni ọọdunrun iku ololufẹ:

1) Iṣẹlẹ nína ara ẹni a ti maa waye diẹdiẹ latẹyinwa ninu ajọṣepọ ololufẹ mejeeji.

2) Kiakia ni ina ifẹ wọn maa n sare jo ni kete ti wọn ba ti dẹnu ifẹ kọ ara wọn.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ija, ìyà ati nina lojoojumọ lo maa n ṣaaju iku ninu iru ajọṣepọ bawọn yii

3) Eni kini ni yoo maa dari ẹnikeji lai ki n fẹ gba imọran ẹlomiran mo tirẹ rara, o maa maa kó ololufẹ rẹ ni papa mọra.

Ko ni fẹ ki o sunmọ ọrẹ tabi alabaṣe to le kọ ọ si oun lọjọ iwaju.

4) Nkan iyatọ kan a ṣẹlẹ to maa ṣokunfa ipaniyan naa bii ki ẹnikeji ni oun ko ṣe mọ tabi pe oun n fẹ ayipada si ija, iya ati nina lojoojumọ.

Eyi yoo jẹ ki ẹni to fẹran lati maa dari ẹnikeji ro pe agbara oun n dinku ninu ajọṣepọ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌ̀rọ̀ Imam yìí ṣe kòńgẹ́ bó ti ń rí láàrin lọ́kọ láya

5) Lẹyin ibeere fun ayipada yii ni iru ẹni to le pa ololufẹ rẹ yii a bẹrẹ si ni mu gbogbo nkan le ninu ajọṣepọ naa.

O maa maa ṣafikun si awọn ofin to fi n dari ololufẹ rẹ, o maa maa ṣọ ọ lọwọ-lẹsẹ pẹlu ara gbigbona.

O tun maa maa dunkooko mọ ololufẹ rẹ pe oun a pa ara oun ti ololufẹ naa ba fi oun silẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIle ejo kan ti so ni odun to koja pe ijoba ipinle ati ibile ko le se igbeyawo

6) Iru ẹni bayii a wa gbe igbesẹ akin to ba de ori gongo.

O le yi ọkan rẹ pada ko kuku moju kuro lara ololufẹ ọhun patapata ki o tẹ siwaju ninu irin ajo aye rẹ.

Tabi ko kuku pa eeyan ni igbẹsan lori ajọṣepọ awọn mejeeji.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Bí aya bá kọ ọkọ rẹ̀ silẹ̀, kó wà láì lọ́kọ̀'

7) Iru ẹni yii a wa bẹrẹ si ni ronu ọna ti yoo gba pa ololufẹ rẹ to ba kọ lati moju kuro.

O maa maa ronu awọn igbesẹ ati ọna ti oun a gba ṣiṣẹ ibi naa ti ko fi ni lẹyin lọjọ iwaju.

O maa lọ ra ohun ija oloro to fẹ lo, tabi ko maa ronu awọn anfani to fi le ka ololufẹ rẹ mọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIwakuwa Awakọ-akero jẹ iwa ti o se iku afawọfa loju popo

8) Ipaniyan: Eyi ni nigba to ba kuku gbẹmi ololufẹ rẹ patapata.

Koda, o le tun pa ọmọ, ẹbi, ara ati ẹnikẹni to ba fẹ kẹfin ipaniyan yii ki aṣiri rẹ ma baa tu lọjọ iwaju.

Dokita Smith ni asiko kan ti igbesẹ yii le yatọ ni ti iru ẹni bẹẹ ko ba ti ṣe iru rẹ ri tẹlẹ.

Eyi tumọ si pe ko ni ni itan iru iṣẹlẹ bẹẹ nitori ko ti ko si àwọn ìfẹ́ ri.

Image copyright @Jane
Àkọlé àwòrán Onimọ yii ṣalaye kikun ohun to n ṣaju ipaniyan nitori ifẹ yii

O ṣalaye fun BBC pe ọpọ igba ni awọn onimọ maa n pe iru iwa ọdaran yii ni: iwa ọdaran ipaniyan nitori ifẹ (Crime of passion)

Ọmọwe Monckton Smith ti kọ awọn agbẹjọrọ, onimọ nipa ironusi ọpọlọ ẹda, ati awọn agbofinro ni ọpọlọpọ igba lori iṣẹ iwadii yii ni UK.

Igbagbọ rẹ ni pe awọn ololufẹ a tubọ ṣọ ihuwasi ara wọn ki ọrọ ifẹ ma la okun ẹmi ololufẹ lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCancer: àpọ̀jù ṣúgà nínú ẹ̀jẹ̀ ń ṣàkóbá fún àgọ́ ara èèyàn