FBI List: A tí mú obinrin kan lára àwọn gbájuẹ̀ ti FBI ń wá- EFCC

Awon odaran Image copyright FBI
Àkọlé àwòrán EFCC gba ọkọ ayọkẹlẹ 30, òògùn ìbilẹ àti ọ̀pọ̀ fóònù lọ́wọ́ àwọn gbájúẹ̀

Àjọ tó ń gbogun ti ìwà jẹgudu jẹra ni orílẹ̀-èdè Nàijíríà ( EFCC) ní ọwọ́ sìkún oun ti tẹ̀ obinrin kan lára àwọn ti FBI ń wa.

EFCC sọ èyí di mímọ lásìkò tí wọ́n ń ba àwọn akọroyin sọ̀rọ̀ ní ìlú Benin ti ṣe olúlu ìpínlẹ̀ Edo, ọgbẹ́ni Muhtar Bello to n soju fun adele ajọ EFCC, Ibrahim Magu sàlàyé pe àwọn kò ni sọ orukọ ọmọbinrin náà nítori ìwádìí ṣì ń lọ lọ́wọ́.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNigeria models: Ẹ má bóra mọ́, ọmọ dúdú dùn lọ́mọbìnrin

EFCC ní iṣẹ́ ọdaran òun kí ó maa ji ojú àwọn ènìyàn ti wọn fẹ jà lólè yóò si fi ránṣẹ́ si àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ ni òkè okun.

Bello ni láàrin oṣu kini ọdun si oṣù kẹjọ ọdun yìí ni àwọn ti mú àwọn gbájuẹ̀ orí ayelujara mẹ́tàle ni ààdọfà ní ìpínlẹ̀ Edo, Delta, àti Ondo tí mẹ́tàlélaàdọ́ta sì ti fọ́ju bale ẹjọ.

Ọ̀gá EFCC ní ọkọ̀ ayọkẹ́lẹ̀ bí ọgbọ̀n, Kọmputa agbélétan, fọóònù, àti òògun ìbílẹ ní wọn ti gba lọ́wọ́ àwọn ọdaran náà.

Bákan náà lo fi kun pé àwọn ti mú ọmọ ìyá meji ti iṣẹ́ ti wọ́n jẹ ki wọ́n ma fi àtẹjisẹ ori ayelujar ránṣẹ lati tan awọn ti ko mọ pé wọ́n fẹ́ gbá awọn ni.