Ondo APC: Irọ̀ ni Ayiloge ń pa mọ gómìnà Akredolu, kìí ṣe ọmọ ẹgbẹ́ wa

Akeredolu Image copyright Akiti@official
Àkọlé àwòrán Ondo APC: Irọ̀ ni Ayiloge ń pa mọ gómìnà Akredolu, kìí ṣe ọmọ ẹgbẹ́ wa

Awọn ohun amayedẹrun ko yatọ nipinlẹ Ondo labẹ Akeredolu - Ayiloge

Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) níjọba ìbílẹ̀ Ifedore nípínlẹ̀ Ondo tí ni àwọn kọ olùdijé ẹgbẹ́ wọ́n, ọgbẹ́ni Banji Ayiloge.

Wọn ni awọn ṣe eyi nitori pe ó parọ́ nígbà tó fẹ̀sùn kan Arakunrin Rotimi Akeredolu to n tukọ ipinlẹ Ondo bayii.

Ayiloge to jẹ́ kọmisọna fún ọ̀rọ̀ tó n lọ ní ìpínlẹ̀ náà kédé pé òun yóò gbégba ipò gómina dije pẹ̀lú Akeredolu ní ọdun tọ ń bọ.

Ìròyin sọ pé nínú ìwé ìròyìn tó ti tí fẹ̀sun kan ìjọba Akeredolu pé ko gbìyànjú rárá nínú ìdàgbàsoke ohun èlò amúlùdún àti pípa owó lábẹ́lé.

Ẹ̀wẹ̀, adarí ẹgbẹ́ APC níjọba ìbílẹ̀ náà lásiko to n ba awọn akoròyìn sọ̀rọ̀ ni ìlú Akure sọ pé Ayiloge ko tilẹ̀ ni káàdì ti a fi le pèé ni ọmọ égbẹ́ bo tilẹ̀ jẹ́ pe o ni ọmọ ẹgbẹ́ ni òun.

Olóri ẹgbẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ àti kọmísọnà fún ètò ìlera Wahab Adegbenro ló ni kò tọ̀nà fún Ayiloge láti parọ mọ gomina nitori pe ó fẹ́ ṣe ìbàjẹ́ rẹ̀.

Ọ̀pọ̀ àwọn alába ṣiṣẹ́ pọ̀ gómònà ló bẹnu ẹ̀tẹ́ lu ìwà ti Ayiloge wu yìí to fi mọ olurànlọ́wọ́ pàtàkì si gomina lóri ìrìnnà, Tobi Ogunleye.

O ni pé ẹnikẹ́ni lo le bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu ìjọba sùgbọ́n irọ́ pipa kò boju mu.