Ọlọ́pàá Nàìjíríà:Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ IMN nìkan là lòdì sí pé kí wọ́n ma ṣé ìwọ́de àyájọ́ Ashura

Aworan ọga ọlọpaa Naijiria Image copyright Twitter/Nigerian Police
Àkọlé àwòrán Ọga ọlọpaa Naijiria,Mohammed Adamu

Ọga agba ọlọpaa Naijiria Mohammed Adamu ti fesi lori ọrọ pe ọlọpaa Naijiria tako iwọde ayajọ Ashura tawọn musulumi n ṣe ni Naijiria.

Loju opo Twitter ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn fi alaye ọrọ yi si,Adamu ni IMN ti wọn fofin de ni Naijiria nikan ni awọn ko gba laaye lati ṣe iwọde naa.

Fun idi eyi,wọn ni ko si idiwọ fun eyikeyi musulumi to ba fẹ ṣe iwọde yi gẹgẹ bi awọn musulumi miran lagbaye ti ṣe n ṣe

Toun ti alaye ọlọpaa yi,ẹgbẹ IMN ni Naijiria ti n ṣe iwọde kaakiri awọn ipinlẹ Naijiria.

Gẹgẹ bi ohun ti ẹgbẹ naa sọ,awọn ọmọ ẹgbẹ awọn ti padanu ẹmi wọn lọwọ awọn ọlọpaa Naijiria lawọn ipinlẹ kan.

Oni ni ayajọ ọjọ kẹwaa ti Muharram to jẹ oṣu kinni ọdun Islam ni eyi ti awọn ẹlẹsin Shi'ite maa n ṣe iwọde lori iku Imam Hussain ibn Ali ninu ogun Karbala.

Agbẹnusọ fun IMN, Ibrahim Musa ni o di dandan ki awọn Shi'ite ṣe iwọde yii paapaa ni àwọn ipinlẹ ariwa Naijiria fun iranti Anabi Hussain naa.

Ṣaaju ni awọn agbofinro Naijiria ti ran Shi'ite leti pe wọn ko le ṣe iwọde kankan mọ lẹyin ti ijọba ti pe IMN ni agbesunmọmi Ikọ̀ aláàbò Nàìjìríà dojú kọ Shiite .

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Òní ni Shi'ite fẹ́ ṣe ìwọ́de lẹ̀sìn wọ́n ní èyí tí ó lòdí sí àṣẹ agbófinró

Nigba ti BBC kan si awọn agbẹnusọ wọn lori ọrọ naa ni Ibrahim ni awọn pinnu lati ṣi ṣe iwọde wọn loni ọjọ Iṣẹgun.

O ni: ọdọọdun ni a maa n ṣe e, a ko le ṣai ṣe ti ọdun 2019 ṣugbọn pẹlu irọwọrọsẹ lai di awọn ẹlẹsin miran lọwọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionShiite: Ẹ̀mí àti ara wa kọ ohun tí ìjọba ń ṣe sìwa láti 2015

Ibrahim ṣalaye siwaju pe: "Bawo ni ako ṣe ni kẹdun iku ọmọ ọmọ Anọbi wa?

Gbogbo agbaye lo n ṣe iwọde ibanikẹdun Anọbi yii, kii ṣe awa nikan, koda London, Washington ati New York ni America.

Tiwa ni Naijiria ko nii yatọ, ẹlẹsin shiite ni tootọ ni wa".

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán A n ṣe iranti iku ọmọ ọmọ Anobi ninu ija Karbala ni - Shiite

Ileeṣẹ agbofinro Naijiria ti paṣẹ fawọn oṣiṣẹ wọn kaakiri Naijiria lati gbe igbesẹ to yẹ fun aabo ati alaafia ni ẹkun wọn.

Oga agba Mohammed Adamu to jẹ adari awọn ọlọpaa ti ni wọn ko gbọdọ faaye gba awọn IMN laaye fun iwọde ti wọn fẹ ṣe loni nitori pe ile ẹjọ ti pe wọn ni agbesunmọmi.

Won ni ki awọn agbofinro dẹkun ohunkohun to ba fẹ dunkooko mọ ẹnikẹni ni Naijiria ati alaafia awọn eniyan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionShiite: Tinúbú, bá Buhari sọ̀rọ̀ kó tú ZakZaky sílẹ̀ kó tó pẹ́ jù

Sheik Ibrahim ti awọn Zakzaky ni irọ ni pe awọn ẹlẹsin oun maa n jale lasiko iwọde yii.

O ni nitootọ ni awọn alaṣẹ maa n fẹ di wa lọwọ ṣugbọn a maa ṣee pẹlu erongba alaafia lọkan ni.

Ibrahim ni: " A gbọdọ ṣe eyi gẹgẹ bi ilana ẹsin wa ṣe fi silẹ ni Islam ti a n sin.

Olorun ti fun wa ni iyọnda ati pe ilana ofin ilẹ Naijiria faaye sile lati ṣe ohun ti eniyan ba fẹ ṣe ti ko ba ti ni wahala ninu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸ̀mí sùn níbi ìkọlù Shiite àti ọlọ́pàá

Ibrahim ni awọn agbaye to jẹ ẹlẹsin Shiite naa ni awọn jọ maa kẹdun iku Imam Hussain to jẹ ọmọ ọmọ Anọbi.

O ni gbogbo ẹlẹsin Islam lo mọ nipa ija to pa ọmọ ọmọ anọbi yii.

IMN ti Ibrahim Zakzakky n dari ni Naijiria ti gbe ijọba Naijiria lọ sile ẹjọ lori bi wọn ṣe pe awọn ni agbesunmọmi.

Ibrahim ni ofin ko de ẹsin awọn rara.

Ṣaaju ni wọn ti n ṣe iwọde pe ki ijọba fi olroi wọn ati aya rẹ to wa latimọle silẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti fofin de iwọde oni ojo Iṣẹgun ti awọn Shiite n gbero yii.

Bẹẹ si ni awọn IMN ti ni awọn agbofinro n gbabọde ati pe ofin kankan ko da ẹsin awọn duro.