Xenophobia: Abala kíní àwọn ọmọ Nàìjíríà yóò padà wálé láti South Africa lọ́jọ́rú

Aṣoju orilẹ-ede Naijiria si South Africa, Godwin Adama Image copyright Twitter/deji_of_lagos

Aṣoju orilẹ-ede Naijiria si South Africa, Godwin Adama, ti wi pe, abala kini ninu awọn ọmọ Naijiria ti ijọba nko bọ wale yoo gbera kuro ni South Africa lọjọru.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹwa lọwọ lati ọdọ News Agency of Nigeria, NAN, Adama sọ pe abala ikini ninu awọn eeyan naa yoo gbera kuro ni South Africa laago mesan aarọ Ọjọru.

O ni "Ọkọ ofurufu akọkọ ti yoo ko ookolelọọdunrun eeyan yoo gbera laago mesan aarọ, nigbati abala keji yoo gbera lọjọbọ."

Ṣaaju ni alaga ileeṣẹ ọkọ ofurufu Air Peace, Allen Onyema, ti yọnda lati ko awon ọmọ ilẹ yi to ba nifẹ lati kuro ni South Africa walẹ lofẹ.

Ni ọjọ aje ni Aarẹ Muhammadu Buhari paṣẹ pe ki wọn ko awọn ọmọ Naijiria to ba nifẹ lati kuro ni South Africa pada wale.

Xenophobia: Dabiri ni Naijiria yóò ṣe ohun tó yẹ́ kí irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí má wáyé mọ́

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Buhari paṣẹ itusilẹ fawọn eniyan Naijiria kuro ni South Africa lẹyẹ o sọka.

Aarẹ Buhari ni ijọba oun ti yanju igbesẹ gbogbo to yẹ lati jẹ ki awọn ọmọ Naijiria kuro ninu ikọlu South Africa.

Aarẹ Buhari aaye ṣi silẹ pupọ fun ẹnikẹni to ba fẹ kuro ni South Africa tẹbi tẹbi bayii.

O tun ni ki Geoffery Onyeama tete mojuto awọn adehun ti wọn ṣe pẹlu ijọba South Africa lati rii pe iru ikọlu yii ko waye mọ sawọn ọmọ Naijiria to fi South Africa ṣe ibujoko.

Ni kete ti Aarẹ Muhammadu Buhari pari ipade pẹlu awọn ikọ to lọ ṣabéwo si South Africa tan to si gbọ abọ wọn lo fi ikede yii sita.

Ahmed Rufai Abubakar lo jabọ ohun ti oju wọn ri ni South Africa fun Aarẹ Buhari ti aarẹ si ni:

Wo àbọ̀ tí wọn jẹ fun Aarẹ Buhari lori ọrọ ikọlu South Africa:

Lọwọlọwọ yii, awọn ọmọ Naijiria ti wọn ṣetan lati pada wa sile ti di oji le ni ẹgbẹta bayii.

Abikẹ Dabiri ati Kabiru Bala to jẹ asoju Naijiria si South Africa ni fifi oro ya oro ni Naijiria ko ni yanju ọrọ to wa nilẹ yii.

Awọn ikọ to lọ South Africa fidiẹ mulẹ fun Aarẹ Buhari pe orilẹ-ede South Africa ko ni akọsilẹ odiwọn iye awọn ti ikọlu naa kan.

Ati pe wọn ko le sọ ni pato bi ikọlu naa ṣe bẹrẹ.

Awọn ikọ naa ni ibudo African Centre for Migration and society (ACMS) ti n da si ọrọ ikọlu si ajoji ni South Africa lati ọdun 1994 nitori ko ṣẹṣẹ bẹrẹ.

Xeno watch ti wọn n lo fi woye irufẹ iṣẹlẹ bayii lati ara iroyin to n jade ṣafihan awọn ikọlu naa ati awọn to ti lugbadi wahala lati ara irufẹ ikọlu yii.

Akọsilẹ wọn fihan pe ikọlu tọdun 2008 ati ti 2015 lo lagbara julọ.

Wọn ni o le ni ọgọta eniyan to ku ninu ikọlu ti 2008 ti ọpọ si di aṣatipo ati arinrinajo lataari aini ile lori mọ.

Tọdun 2015 ni akọsilẹ wọn ni apa Durban ati ni Johannesburg.

Ninu eyi ni ikọlu ti waye fawọn ajeji ni South Africa ki awọn ọmọ ogun ilẹ̀ tó yanju ẹ.

Kini ijọba Naijiria ni lọkan fun awọn ti wọn n ko bọ pada sile -Abikẹ Dabiri?

Ko tii si ọna idani pada sipo ti a la kalẹ fawọn ti a n ko bọ lati South Africa - Abikẹ Dabiri.

Ijọba apapọ ti sọ pe ko tii si iranlọwọ kankan fun awọn ọmọ Naijiria ti wọn n bọ lati South Afrika lọjọ ru.

Image copyright Air peace
Àkọlé àwòrán Baluu Air Peace ṣetan lati gbe àwọn eniyan Naijiria

Alaye yii lo tẹnu alaga igbimọ to wa fun ibojuto ọrọ ọmọ Naijiria loke okun, Abike Dabiri jade ni ilu Abuja lọjọ Aje.

Kò tíì sí ìrànlọwọ owó f'àwọn ọmọ Nàìjíríà tí ń bọ láti South Africa -Abike Dabiri.

Abikẹ Dabiri ni: ko si eto ifunni lowo tabi iranlọwọ imu-pada-bọ-sipo lati ọwọ ijọba apapọ fun wọn lataari rogbodiyan to bẹ silẹ ni orilẹ-ede South Africa.

O tesiwaju ninu ọrọ rẹ wi pe, ijọba apapọ yoo ri i daju pe ijọba ilẹ South Africa dide fun iranlọwọ awọn ọmọ Naijiria ti wọn ba dukia wọn jẹ.

Ṣe saaju ni ijọba apapọ ti paṣẹ ki Minisita fun ọrọ ilẹ okeere, Geoffery Onyeama, lati kan si gbogbo ẹni ti ọrọ kan lati dẹkun idunkooko mọ awọn ọmọ Naijiria.

Image copyright Air Peace
Àkọlé àwòrán Air Peace ti setan lati maa ko awon omo Naijiria bo

Aarẹ Muhammadu Buhari lo pasẹ yii nigba ti Aṣoju orilẹ-ede yii ni ilẹ South Africa, Ahmed Rufai Abubakar ṣe abẹwo si i lori iṣẹlẹ ikọlu si awọn ajoji ni outh Africa.

Ijọba Naijiria lo ti n pe fun ẹbun gba ma-binu fun awọn ọmọ Naijiria latari dukia ti wọn bajẹ ni ilẹ naa.

Buhari ti pe ṣaaju fun asọyepọ laarin ọlọpaa ilẹ yii ati ti South Africa lati daabo bo dukia ati ẹmi awọn ọmọ Naijiria sugbọn ti o ja si pabo.

Related Topics