Abducted Professor: Ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ti ké sì àwọn ọlọ́pàá lórí ikú Ọ̀jọ̀gbọ́n Okedayọ

Ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ Image copyright ASUU
Àkọlé àwòrán Ọ̀jọ̀gbọ́n Gideon Òkédayọ tí wọ́n jí gbé lọ́sẹ̀ tó kọjá kú

Ẹgbẹ awọn olukọ fasiti ti Naijiria (ASUU) ti ke si ile iṣe ọlọpaa ati awọn eleto aabo lati ṣewadii iku ati lati ṣafihan ẹnikẹni to ba lọwọ ninu iku Ọjọgbọn Gideon Okedayọ ti wọn ri oku rẹ ninu igbo ni ọjọ kesan, oṣu kẹsan, ọdun yi.

Alaga ẹgbẹ naa ti ẹka ile iwe giga fasiti imọ ẹrọ ti Ipinlẹ Ondo, Dokita Dipo Akomolafe, lo fọrọ naa sita lọjọ Iṣẹgun nilu Okitipupa

Image copyright Facebook/Gedeon Okedayo
Àkọlé àwòrán Iku alumuntu ojiji ti ko sẹni to yẹ mọ nipa eto aabo Naijiria

Ọjọgbọn Gideon Okedayọ to jẹ olukọni ni ile iwe giga fasiti imọ ẹrọ ti Ipinlẹ Ondo, lo padanu ẹmi rẹ ninu igbekun awọn ajinigbe.

Ọjọ karun un, oṣu karun un, ọdun yii ni iroyin kan pe wọn n wa ọjọgbọn yii ki wọn to gba ipe pe ọdọ awọn ajinigbe lo ti ha si.

Iroyin ti a gbọ ni pe wọn ji ọjọgbọn Okedayọ gbe nigba ti o n lọ si Igarra ni ipinlẹ Edo to jẹ ilu rẹ.

Alaga ajọ awọn oṣiṣẹ ni fasiti Ondo yii, Temidayo Temola ṣalaye pe lootọ ni ọrọ yii ṣẹlẹ si ibanujẹ gbogbo awọn oṣiṣẹ fasiti naa.

Nigba ti BBC kan si alukoro awọn agbofinro ti ẹjọ wiwa ọjọgbọn yii wa ni akata rẹ, o fidiẹ mulẹ pe lootọ ni ọjọgbọn yii ti doloogbe.

Alukoro awọn ọlọpaa ni ipinlé Edo, Chidi Nwabuzo, ni nitootọ ni wọn ti ri oku ọjọgbọn yii loju popo lẹyin ti wọn gbẹmi rẹ.

Ọjọgbọn Igbasan to jẹ igbakeji adari ile iwe giga fasiti naa ni ọrọ naa kanilaya nigba ti BBC kan sii.

O ni oun ibanujẹ pata ni nitori agboole awọn ọjọgbọn ti padanu ọlọpọlọ pipe pẹlu iku ọjọgbọn yii lasiko yii.