Mental Health: Ko yẹ ki ìrònú ya èèyàn ní wèrè, ṣo ẹ̀dùn ọkàn rẹ síta!

Mental Health: Ko yẹ ki ìrònú ya èèyàn ní wèrè, ṣo ẹ̀dùn ọkàn rẹ síta!

Ọpọ ironu lo n ṣokunfa ifunpa giga to n ṣakoba fun ilera ọkan ati ara ati ọpọlọ ẹda.

Awọn onimọ n fọn rere pataki nini ilera pipe laifi ironu ṣe ara ẹni lese nitori pe ohun ti ko to ṣi maa ṣẹku.

Ajọ ilera iṣọkan agbaye sọrọ lori ironu yii pe:

Ti ironu ba pọju lo maa n fa irẹwẹsi ọkan ni eyi to maa n jẹ ki ẹlomii fẹ gbẹmi ara rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ironu ko da nkan, ọrẹ tujuka!

Ayajọ gbigbogunti iṣeku pa ara ẹni.

Suicide Prevention: ìwọ́de yìí wáyé láti gbógun ti pípa ara ẹni

Pípa ara ẹni kìí ṣe ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro rárá -Glittow

Ajọ ilera agbaye ni ẹmi kan maa n sọnu laarin ogoji iṣẹju aaya lataari pe ẹni naa pa ara rẹ ni.

O le ni ẹgbẹrin eniyan to n pa ara wọn lọdọọdun gẹgẹ bi akọsilẹ WHO ṣe sọ ati pe eyi ni ọna ijade laye keji laarin awọn ọdọ ti ọjọ ori wọn ko ju mẹẹdogun si mọkandinlọgbọn.

Bẹẹ ajọ ilera agabye ni ọpọ kii fẹ sọrọ nipa rẹ.

Ọpọlọpọ awọn ajọ lo ti n sọrọ nipa rẹ ni Naijiria bayii bii àwọ GliHow Hope Foundation ti wọn rin kiri ni ipinlẹ Eko lati fi sami ayajọ ọjọ gbigbogun ti pipa ara ẹni lagbaye.

Oluwatobi Abodunrin, Monique ati Oluṣeyi Ṣorẹmẹkun ti wọn ba BBC sọrọ lasiko iwọde gbogun ti ipara ẹni to n gbilẹ laarin awọn ọdọ Naijiria.

wọn ni ki iru ẹni to n ronu lati pa ara rẹ yii ro ti ẹbi, ara, ọrẹ ati iyekan to fẹ fi silẹ ninu ibanujẹ.

Iṣẹ iwadii kan ni America fidiẹ mulẹ pe fun ẹnikan ṣoṣo to ba pa ara rẹ, eniyan marundinlogoje lo maa mọ ọ lara pe ẹni awọn lọ.

Omowe Julie Cerel ti fasiti Kentucky ṣiṣe lori iru ipa ti ẹni to pa ara rẹ maa n ni lara ẹbi, ara, ọrẹ ati ojulumọ.

Eyi lo mu wa woye àwọn ọna ti eeyan fi le ṣi ọkan ẹni to n ronu lati pa ara rẹ kuro ninu ironu bẹẹ lasiko yii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Wọn maa n ni igbagbọ pe awọn nikan ni wọn wa lasiko ti ero yii n wa sọkan wọn

Kọkọ bẹrẹ si ni ba a sọrọ ṣaaju ohunkohun:

Ko si ọna ti eeyan ko le gba fi ba iru wọn sọrọ.

Ṣaa ti lo ọnakọna to ba wu ọ lati fi ba iru ẹni naa sọrọ gẹgẹ bi Emma Carrington to jẹ agbẹnusọ Rethink UK ṣe sọ fun BBC.

O ni fi ara balẹ ba iru ẹni naa sọrọ laikanju rara ki o ma baa muu ronu sii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ajọ WHO ni o ṣe pataki ki awọn ọdọ mọ nipa iṣẹ ọwọ kan ti yoo mu ironu wọn dinku

Imọran tootọ lati ọkan wa lasiko naa:

 • Wa ibi to dakẹ ti ẹ ti le jó sọrọ asọyepọ.
 • Rii pe ẹyin mejeeji ni asiko to pọ to lati fi jọ jiroro.
 • Ma je ki aya rẹ ja ti o ba sọ nkan ti ko tọna daadaa.
 • Maa wo oju iru ẹni bẹẹ nigbagbogbo lasiko ijiroror yin nitori pe oju lọrọ wa.
 • Fi suuru ṣalaye pataki ki iru ẹni bẹẹ yan l;ati wa laaye ki o fara balẹ gbọ ohun to n kọọ lominu.
 • Ma sare fun un ni ọna abayọ lai fi oju iru ẹni bẹẹ wo iṣoro to n yọ ọ lẹnu.
 • Maa beere ibeere to nilo idahun to pọju bẹẹni tabi bẹẹkọ
 • Rii pe wọn mọ ibi to yẹ ki wọn lọ gba imọran lọdo awọn akọṣẹmọṣẹ ninu iṣẹ ọpọlọ.

Ta ni o le ronu lati pa ara rẹ lawujọ?

Irufẹ awọn to n ronu lati pa ara wọn ko ni gbendeke ọjọ ori kan ni pato.

Lọdun 2016 ni a rii pe ọkunrin pọ to pa ara wọn ju obinrin lọ.

Ṣugbọn odiwọn yii yatọ lati orilẹ-ede kan si ikeji ati ni asiko ọtọọtọ.

Orilẹ-ede Russsia lo ni diwọn awọn ti wọn pa ara wọn ju lọkunrin ni agbaye lọdun 2016 ni eyi ti wọn fi fidiẹ mulẹ pe ọti ati ironu nii ṣe pẹlu pipa ara wọn lasiko naa.

Ṣugbọn ọpọ ninu awọn ti wọn maa n pa ara wọn kan maa n deede ronu pe o to gẹẹ ni, ki opin de lasiko naa lojiji.

Iwadii fihan pe ti eeyan ba ti n ronu aroju, to ni iṣoro bii ti owo ati ikọsilẹ tabi aisan kan ni o maa n ronu lati pa ara rẹ.

Iwadii WHO ni awọn to n ronu, ti wọn ni idojukọ, ti wọn n koju iwa ipa kan tabi ti wọn ti padanu nkan tabi ti wọn ro pe awọn ko ni alafọrọlọ lo maa n saaba pa ara wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Koda ti ọrọ ẹni naa ko ba ye ọ to dakun ma baa ja lasiko yii

Ọpọ eeyan lo maa n ro pe ko si ẹni ti awọn fi oju jọ koda ti wọn ba wa laarin ero pupọ.

Idi niyii ti a fi gbọdọ ran ara wa lọwọ lati din pipa ara ẹni ku lawujọ.

Kini awujọ le ṣe?

Ajọ olera agbaye WHO ni ijọba le gbogun ti pipa ara ẹni lawujọ nipa ṣiṣe awọn nkan wọnyii:

 • Fifopin si idẹyẹsi ki awọn eniyan le maa sọrọ sita.
 • Riran awọn ọdọ lọwọ lati kọ iṣẹ ọwọ ti wọn a fi le maa koju ọjọ iwaju wọn paapaa nile iwe wọn.
 • Kikọ awọn oṣiṣẹ nipa ṣiṣe amojuto iwa iparaẹni ni kete ti wọn ba ti kẹfin iru ẹni bẹẹ.
 • Kiko awọn nkan ipara ẹni kuro nilẹ
 • Dida awọn eniyan bayii mọ ati fifi igba gbogbo kan si wọn loorekoore.

Yiya itan ati arọba sọtọ lori pipa ara ẹni:

Ajọ awọn ọlọpọlọ ti ni iyatọ wa laarin awọ=n itan kan to wọpọ ati igbagbọ ti kii ṣe ootọ.

Okan nibẹ ni pe sisọrọ nipa pipa ara ẹni maa jẹ ki eeyan ronu lati pa ara rẹ.

Ṣugbọn Beyond Blue ti Australia ti fihan pe sisọrọ nipa pipa ara ẹni le mu iru ero bẹẹ kuro lọkan ẹni to fẹ pa ara rẹ.

Julia Gillard to ṣaaju iwadii oni ọọdunrun eeyan yii fihan pe awọn eniyan kii fẹ gba ẹni to fẹ pa ara rẹ nimọran nitori ẹru.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọpọ ẹni to n ronu a maa wa ninu ewu

Kọ lati jẹ Adajọ lori aye ẹni naa:

"kii ṣe dandan ki o jẹ oṣiṣẹ eleto ilera ki o too le gba iru ẹni bẹẹ ni imọran to yẹ.

Ṣaa jẹ ẹni ti ọkan rẹ mo to ṣetan lati sọrọ" ni imọran Gillard.

Carrington ni ki o rii pe o ko sọ ara rẹ di adajọ lori aye ẹni naa.

Koda o le ṣi oju wọn si ọna abayọ si iṣoro wọn ti awọn gan an ko ronu nipa rẹ.

Ba wọn sọrọ nipa oni ati ohun to ṣẹlẹ si rere ninu aye wọn:

"Ti ọkan rẹ ko ba balẹ lori ẹnikan, bẹrẹ si ni beere wọn lojoojumọ. Ki o maa beere bi nkan ṣe ri lọdọ wọn ni asiko kọọkan. Eyi ṣeeṣe ko fi wọn lọkan balẹ lasiko yii".

O yẹ kii o sọ ara rẹ di irufẹ ẹni ti wọn le fọkan tẹ ki ọkan wọn le bale si ijiroro yin papọ ti wọn a fi yi ọkan wọn pada.