Justice For FUOYE: Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ọlọ́pàá ló bẹ̀rẹ̀ ìbọn yínyìn tó dá wàhálà sílẹ̀!

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAwọn akẹkọọ naa ni awọn ko kọlu iyawo gomina ipinlẹ Ekiti lasiko iwọde wọn.

Ori ẹrọ ayelujara n gbona jainjain pẹlu bi awọn akẹkọọ Ile-Iwe giga ti Ọyẹ-Ekiti, FUOYE se n bere fun iwadii lori isekupani awọn ọmọ ile iwe awọn meji.

Lara awọn ọmọ ile iwe naa fi si oju opo Twitter wọn wi pe awọn ọlọpaa lo kọkọ da ibọn bo wọn ko to di wi pe awọn akẹkọọ naa wa yari.

Bakan naa ni awọn akẹkọọ ni awọn ọlọpaa ko lati jẹ ki awọn lọ si ile awọn obi awọn lẹyin ti awọn alasẹ ti ile-iwe naa pa.

Ni Ọjọru ọsẹ yii ni Adari ile-iwe naa pasẹ ki wọn ti ile iwe naa pa lẹyin ti wọn fẹsun kan awọn akẹkọọ pe wọn n fẹhọnu han lọna aitọ.

Amọ, awọn akẹkọọ naa ni aisi ina ojoojumọ lo mu ki awọn fi ẹhọnu han, eleyii ti o sumọ ibi ti Iyawo Gomina ipinlẹ Ekiti, Bisi Fayemi ti n se ironilagbara ni agbegbe naa.

Bakan naa ni awọn ọlọpaa sọ wi pe awọn ko pa akẹkọo kankan, ati wi pe awọn akẹkọọ lo se ikọlu si wọn.

Ṣé lóòtọ́ ni akẹ́kọ̀ọ́ fásitì FUOYE kan kú lọ́wọ́ ọta ìbọn ọlọ́pàá l'Ekiti?

Awuyewuye ṣi n ja lori wahala to waye ni ilu Ọyẹ Ekiti laarin awọn akẹkọọ, awọn araalu atawọn agbofinro ni ọjọ Iṣẹgun.

Ni bi a ṣe n sọrọ yii, iroyin ti o n tẹ wa lọwọ sọ pe akẹkọọ kan ti orukọ rẹ n jẹ Oluwaṣeyi Kẹhinde, akẹkọọ ipele kini ni ẹka ẹkọ imọ nipa eto Ọgbin ni fasiti naa ti jade laye nitori iṣẹlẹ ọhun.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Aarẹ ẹgbẹ akẹkọ ni fasiti FUOYE, Ọgbẹni Oluwaseun Awodọla ni awọn ọlọpaa lo kọkọ bẹrẹ si nii kọlu awọn akẹkọọ naa.

O tun ni pe ibọn ti wọn yin si laidawọduro lo ṣokunfa bi awọn akẹkọọ ti ṣe bẹrẹ si nii ju okuta lati fi ẹhonu han.

Ọgbẹni Awodọla ni ko si otitọ ninu iroyin to n kaakiri pe iwọde awọn lawọn fi koju ija si iyawo gomina ipinlẹ naa to wa ṣe abẹwo si ilu Ọyẹ.

O ni iwọde ẹhonu ti awọn akẹkọọ ṣe lati fi pariwo ohun ti oju wọn n ri nipa aisi ina ọba nibẹ ti pari fun ọpọlọpọ wakati ki iṣẹlẹ buruku ti a n sọrọ rẹ yii to bẹrẹ.

Nigba ti BBC News Yoruba tun kan si ẹni to jẹ adari ẹka to n mojuto igbayegbadun awọn akẹkọọ lọgba fasiti naa, Ọmọwe Malọmọ, o ni kii ṣe inu Ọgba fasiti ọhun ni iṣẹlẹ naa ti bẹrẹ.

Ki ni Ọlọpaa sọ?

Image copyright Bamidele Ademola Olateju

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ko mọ nipa iku akẹkọọ kankan nileewe naa ati pe gbogbo iroyin ti o n lọ kaakiri lori ẹrọ ayelujara kii ṣe ootọ.

Ninu atẹjade kan ti o fi ranṣẹ si akọroyin BBC News Yoruba, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Caleb Ogu ṣalaye pe awọn akẹkọọ to n ṣewọde naa ni wọn kọlu ọlọpaa.

O ni koda wọn kọlu awọn ọkọ to ba iyawo gomina Bisi Fayemi kọwọrin nibi ti wọn ti ba awọn ọkọ jẹ ti wọn si tun ṣiwọ lu awọn ọlọpaa ti wọn wa nibẹ lati rii pe alaafia jọba.

Amọṣa, o ni iwadii ṣi n lọ lori iṣẹlẹ naa.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń fẹ̀họ́nú hàn nítorí iná ọba tó ń ṣe ségesège

Awọn Alakoso ile iwe giga fasiti ijọba apapọ to wa ni Oye-Ekiti, (FUOYE) ti bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu ifẹhọnu han awọn akẹkọọ Ile- Iwe naa.

Paapaa awọn to da rogbodiyan silẹ ni agbeegbe naa ni eyi ti o da alaafia Oye ru lasiko ọhun.

Image copyright Bamidele Ademola Olateju

Awọn akẹkọọ naa n fẹhọnu han nitori ina ijọba to n ṣe segesege ni awọn yara ikẹkọọ gbogbo to wa ni fasiti naa.

Agbẹnusọ Ile-iṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Caleb Ikechukwu ni awọn akẹkọọ naa fi ina si oko wọn.

Image copyright Bamidele Ademola Olateju

Wọn si tun gba ibọn awọn ọlọpaa meji, amọ, awọn akẹkọọ fẹsun kan ọlọpaa pe wọn pa akẹkọọ lasiko ifẹhọnu han, sugbọn ọlọpaa ni ko si ohun to jọ ọ.

Bakan naa ni iroyin ni wi pe Iyawo Gomina Ipinlẹ Ekiti, Bisi Fayemi rin si asiko rogbodiyan yii ni.

Image copyright OTHERS
Àkọlé àwòrán Ìròyìn ní orí ló kó ìyàwó gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti yọ lẹ́yìn tí ìfẹ̀họ́nú àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ dá rògbòdìyàn sílẹ̀.

Asiko naa ni wọn si ṣe ikọlu si ọkọ rẹ, to jẹ wi pe ori lo ko o yọ ninu ikọlu naa lẹyin ti awọn ọlọpaa lo ‘iṣe commando’ lati mu u kuro nibi rogbodiyan naa.

Image copyright OTHERS
Àkọlé àwòrán Àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ tó ń fẹ̀họ́nú hàn se ìkọlù sí Fayemi

Awọn alaṣẹ ile -iwe naa ti kilọ fun awọn akẹkọọ lati ma ṣe da eto ẹkọ saa naa ru, ki wọn si ranti pe awọn kọ lo wa ni idi eto ina mọnamọna ni ipinlẹ Ekiti.

Image copyright Bamidele Ademola Olateju
Àkọlé àwòrán Ìròyìn ní orí ló kó ìyàwó gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti yọ lẹ́yìn tí ìfẹ̀họ́nú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ dá rògbòdìyàn sílẹ̀.