Tribunal: Ẹ wo márùn ún lára àwọn tí ilé ẹjọ́ dá dúró lẹ́yìn ìdìbò ọdún 2019

Abiola Ajimobi, Dino Melaye ati Dayo Adeyẹye Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Ẹ wo márùn ún lára àwọn tí ilé ẹjọ́ ti yọ kúrò nípò lẹ́yìn ìdìbò ọdún 2019

Lẹyin idibo gbogboogbo to waye loṣu keji ọdun yii ni ọpọlọpọ awuyewuye ti n ṣelẹ lori esi idibo naa ti ajọ eleto idibo INEC fi lede.

Awuyewuye naa lo n waye lẹyin ti awọn kan sọ pe awọn lo jawe olubori ninu idibo naa sugbọn ti INEC gbe ipo wọn fun elomiran.

Leyin eyi ni wọn gba ile ẹjọ to n gbọ ọrọ idibo lọ, ti oriṣiriṣi idajọ si ti n jade.

Awọn idajọ yii lo ti mu ki awọn kan to ti wa nipo tẹlẹ kẹru wọn pada sile, lara awọn ti ileẹjọ da pada sile lẹyin ipẹjọ idibo ree.

Abiola Ajimobi - Ọyọ

Abiola Ajimobi to jẹ gomina ana nipinlẹ Ọyọ lo gbe apoti idibo fun ipo sẹnetọ fun ẹkun idibo guusu ipinlẹ Ọyọ.

Ṣugbon o fidi rẹmi, lẹyin naa lo gba ile ẹjọ lọ pe, oun ni o yẹ ki INEC kede gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori, ni eyi ti ile ẹjọ to n ṣegbẹjọ ọrọ naa ni bẹẹkọAjímọ̀bí lè pe Ọlọ́run lẹ́jọ́ bí ìdájó kò bá tẹ́ ẹ lọ́rùn -Kọla Balogun .

Adajọ Anthony Apkovi ti o ṣoju igbimọ ẹlẹni mẹta ti o n risi igbẹjọ naa lo kede abajade iṣẹ iwadii wọn lọjọ Iṣẹgun pe Kọla Balogun lo jawe olubori, nitori naa, ki Ajimọbi lọ wa ibi joko si.

Dayo Adeyẹye - Ekiti

Ibo sipo Sẹnetọ ti wọn di loṣu keji ọdun yii lo gbe Dayo Adeyẹye wọle sile igbimọ aṣofin l'Abuja.

Sẹnetọ Adeyéye, to jẹ alaga Ile igbimọ asofin lori ọrọ iroyin ati awujọ ni ile ẹjọ to n gbọ ẹjọ ẹsun to ni i ṣe pẹlu idibo ni ko kogba kagbọn rẹ pada sile bayii.

Eyi waye lẹyin ti Sẹnetọ Biodun Olujimi fariga pe Adeyẹye kọ ni ojulowo ẹni to bori idibo naa ni Ekiti, ni eyi ti ile ẹjọ ti faramọ.

Nigbati o n ṣedajọ lori idibo naa lọjọ Iṣẹgun, igbimọ ẹleni mẹta ti adajọ Daniel Adeck dari rẹ wọgile ibo to gbe Dayo Adeyẹye sipo Sẹnetọ lẹkun idibo guusu Ekiti, lẹyin naa lo kede pe Sẹnetọ Biodun Olujimi gan ni ojulowo ẹni to jaweolubori ninu idibo naa.

Orji Uzor Kalu - Delta

Ile ẹjọ to n gbọ ẹjọ ẹsun to ni i se pẹlu idibo sile igbimọ aṣofin ni ipinlẹ Delta naa tun ti wọgile ibo to gbe Orji Uzor Kalu wọle.

Orji ni ẹni to jẹ gomina ana nipinle ọhun.

Nigba ti o n ṣedajọ rẹ lọjọ Aje, igbimọ ẹlẹni mẹta ti adajọ I. P. C Igwe n dari ni olupẹjọ, Mao Ohuabunwa ti fi idi ẹjọ to pe mulẹ.

Saaju ni olupẹjọ ti rọ ile ẹjọ naa lati wọgile ibo to gbe ọgbẹni Kalu wọle, nitori ko wa pẹlu ibamu ofin to ni i ṣe pẹlu ọrọ eto idibo ti ọdun 2010.

Ohabunwa sọ fun ile ẹjọ pe, INEC yọ awọn ibo kan ṣeyin nigba ti wọn fẹ ka ibo naa, ati pe, ọpọlọpọ eeyan to yẹ ki wọn dibo ni ajọ INEC ko gba laaye lati dibo.

Leyin atotonu olupẹjọ ati olujẹjọ ni adajọ ọhun da ibo naa nu, to wa paṣe pe ki wọn tun ibo naa di ni awọn agbegbe kan laarin oṣu mẹta.

Image copyright @OUKtweets
Àkọlé àwòrán Orji ni ẹni to jẹ gomina ana nipinle ọhun.

Dino Melaye -Kogi

Lara awọn ti ile ẹjọ to n gbẹsun idibo da pada sile ni Sẹnetọ Dino Melaye to n soju ẹkun idibo iwọ oorun ipinlẹ Kogi.

Ikọ ẹlẹni mẹta to n risi ipẹjọ ti adajọ A.O Chijioke n dari lo ṣedajọ naa lọjọ kẹtalelogun, oṣu kejọ ọdun yii.

Adajọ naa wa paṣẹ fun ajọ INEC lati tun ibo naa di laarin aadọrun un ọjọ.

Sugbọn Sẹnetọ Melaye ti ni ti adajọ ni o n sọ, oun yoo pe ejọ kotẹmilọrun.

Lazarus Ogbe - Ebonyi

Ile ẹjọ to n ṣegbẹjọ ẹsun idibo ni Abakaliki ti ni ki ọgbẹni Lazarus Ogbe, ọmọ ẹgbẹ PDP to n soju ẹkun guusu Ezza kẹru rẹ kuro nile aṣoju l'Abuja pada sile.

O ni ki ẹni ti wọn kede ni ipinlẹ Ebonyi yii kuro ni ipo naa nitori naa lo ṣe da ibo to gbe e wọle nu.

Ile ẹjọ naa kede Chinedu Ogah, lati ẹgbẹ APC, gẹgẹ bi ojulowo ẹni to jawe olubori ninu idibo naa.

Kini o ti ṣẹlẹ sẹyin?

Tribunal: Olujimi ló wọlé ní ìdìbò Ekiti kìí ṣe Adeyeye

Image copyright others
Àkọlé àwòrán Sẹ́nátọ̀ Biodun Olujimi ló gba ilé ẹjọ́ tó ń gbẹ́jọ́ ẹ̀sùn ìdìbò lọ, lẹ́yìn ìdìbò sílé Asòfin Àgbà ti ọdún 2019.

Ile ẹjọ to n gbọ ẹjọ ẹsun to ni i se pẹlu idibo si Ile Igbimọ Asofin ni ipinlẹ Eko ti fagile idibo to gbe Alaga Ile Igbimọ Asofin lori ọrọ Iroyin ati Awujọ, Sẹnatọ Dayo Adeyeyẹ.

Oun ni o dije labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ni Osu Keji, ti ọdun 2019.

Ajọ igbẹjọ oni eniyan mẹta ti Adajọ Agba, Danladi Adeck se adari fun naa kede oludije PDP.

O ni pe adari tẹlẹri fun ọmọ ẹgbẹ to kere julọ ni Ile Igbimọ Asofin, Sẹnatọ Biodun Olujimi ti ẹgbẹ oselu PDP pe oun lo wọle ninu idibo naa si Ile Igbimọ Asofin gẹgẹ bi asofin to n ṣoju guusu ipinlẹ Ekiti.

Ninu Idajọ naa, ile ẹjọ wọgile awọn ipinlẹ ti magomago ti waye ninu idibo naa, eleyii ti o si mu ki Olujimi ko bori pẹlu ibo to to 54,894 nigba ti Adeyeye ni ibo to to 52,243.

Adajo naa ni Olujimi bori ninu idibo naa nitori o fihan gbangba niwaju ofin pẹlu ẹri wi pe magomago waye ni awọn ijọba ibilẹ bii Ikere, Gbonyin ati Emure.

Amọ, o ṣeeṣe ki Adeyeye gbe ẹjọ naa lọ si ile-ẹjọ kotẹmilọrun laaarin ọjọ mẹrinla.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAPC: òfin NYSC ti APC fi mú mi ni wọ́n kò lò fi mú Ajimọbi tí a kò jọ sìnrú ìlú