EFCC- Diezani: Ilé ẹjọ́ ti gbéjilé ẹ̀ṣọ́ ara Diezani tó tó $40m pátápátá

Diezani Allison-Madueke Image copyright WOLE EMMANUEL
Àkọlé àwòrán Ilé ẹjọ́ tó ń gba ẹjọ́ ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu tí Àjọ EFCC pé mọ Diezani Allison-Madueke ti gbẹ́ṣẹ̀ lé ohun ẹ̀ṣọ́ ara rẹ̀.

Ile ẹjọ giga ni ipinlẹ Eko ti fun ijọba orilẹede Naijiria laṣẹ lati gbe ẹṣẹ le ohun ẹsọ ara Minisita fun ọrọ epo bẹntirol tẹlẹri, Diezani Allison-Madueke. lori ẹsun iwa ajẹbanu.

Adajọ Nicholas Oweibo sọ wi pe Madueke ati Agbẹjoro Aku Kalu kuna lati fi ẹri to daju lede idi ti ijọba ko ṣe gbọdọ gbe ẹṣẹ le ẹṣọ ara (tirinkọwọ, tirinkẹsẹ, ẹsọ ọwọ ati tọrun, ẹrọ ilewọ iphone) ti o to ogoji miliọnu owo ilẹ okeere dọla.

Ọkan lara awọn oniwadii fun Ajọ EFCC ni lẹyin ọdun 2012 ti arabinrin naa di minisita, lo bẹrẹ si ni ko ọrọ ẹṣọ ara naa jọ.

Ajọ EFCC ni o da awọn loju wi pe nipa ọna ẹburu ati magomago, pẹlu lilu owo ilu ni ponpo ni Madueke fi ko ọrọ naa jọ.

Ti a ko ba gbagbe, Minisita tẹlẹri naa lo pe ẹjọ mọ Ajọ EFCC wi pe wọn wọle oun lọna aitọ, ti wọn si ko awọn ohun ẹṣọ ara rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAPC: òfin NYSC ti APC fi mú mi ni wọ́n kò lò fi mú Ajimọbi tí a kò jọ sìnrú ìlú