nnnnnnnnnnnnnnnnnn
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Justice For FUOYE: Ṣé lóòtọ́ ni akẹ́kọ̀ọ́ fásitì FUOYE kan kú lọ́wọ́ ọta ìbọn ọlọ́pàá l'Ekiti?

Awuyewuye ṣi n ja lori wahala to waye ni ilu Ọyẹ Ekiti laarin awọn akẹkọọ, awọn araalu atawọn agbofinro ni ọjọ Iṣẹgun.

Ni bi a ṣe n sọrọ yii, iroyin ti o n tẹ wa lọwọ sọ pe akẹkọọ kan ti orukọ rẹ n jẹ Oluwaṣeyi Kẹhinde, akẹkọọ ipele kini ni ẹka ẹkọ imọ nipa eto Ọgbin ni fasiti naa ti jade laye nitori iṣẹlẹ ọhun.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Aarẹ ẹgbẹ akẹkọ ni fasiti FUOYE, Ọgbẹni Oluwaseun Awodọla ni awọn ọlọpaa lo kọkọ bẹrẹ si nii kọlu awọn akẹkọọ naa.

O tun ni pe ibọn ti wọn yin si laidawọduro lo ṣokunfa bi awọn akẹkọọ ti ṣe bẹrẹ si nii ju okuta lati fi ẹhonu han.