Mo kọ̀ láti ṣe àpèjẹ 'Reception'lẹ́yìn ìgbéyàwó mi nítorí...
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

No reception wedding: Adewale ni àpèjẹ kò ṣe pàtàkì sí òun

Kìí ṣe dandan ni ki eeyan pe apejẹ lẹyin igbeyawo -Adewale

Laipẹ ni iroyin iwe ipe si ibi ase igbeyawo laarin arakunrin Adewale Olamilekan Yussuf ati omidan Blessing Ijeoma Oghota gba ayelujara kan.

Ohun to ṣajeji ninu iwe ipe sibi ase igbeyawo naa ni pe wọn ni ko ni si apejẹ lẹyin isin igbeyawo ni eyi to ya awọn eeyan lẹnu.

Koko to jọ awọn eeyan loju ni pe ọmọ iran Igbo lati ipinlẹ abia gba fun ọmọ Yoruba lati ipinlẹ Oṣun pe ki apejẹ ma wa lẹyin isin igbeyawo wọn lẹnu.

Awọn lọkọlaya yii ṣalaye idi ti awọn ṣe ni irufẹ ipinnu yii fun BBC Yoruba lẹkunrẹrẹ.

Ogbeni Adewale ṣalaye pe ori ayelujara ni awọn ti pade ti ina si wọ ki ẹbi, ara ati iyekan to ba wọn yọ ayọ igbeyawo wọn.

Ọkọ iyawo to jẹ onimọ nipa ayarabiaṣa ni kii ṣe owo ti awọn maa na nibi ase apejẹ lẹyin igbeyawo ni ko si, ṣugbọn o wu oun pe ki ero wa sibi ileri ifẹ oun ni ṣọọṣi ju ki wọn wa si apejẹ lasan lọ ni.

Adewale ni oun ko lodi si ṣiṣeapejẹ lẹyin igbeyawo fun ẹni to ba wu tabi to lowo lati ṣẹ ẹ.

Nigbẹyin, o ṣalaye bi awọn eniyan kan ṣe pada ṣe apejẹ ranpẹ fun tọkọtaya fi ya wọn lẹnu lẹyin isin igbeyawo wọn to waye lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2019 yii.