Ìjọba ti ṣetán láti tọ́jú àwọn ọmọ Naijiria tó ń bọ padà láti South Africa
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Xenophobia: Naijiria á kọ́kọ́ pèsè ọ̀nà láti bá ẹbí sọ̀rọ̀ fún wọn

Awọn eniyan mejidinlọgọsan ni wọn ti fidiẹ mulẹ pe wọn n gbera.

Wọn n gbera bayii lẹyin ti wọn ti da wọn duro fun ọpọlọpọ wakati lataarọ.

Papapkọ ofurufu Muritala Muhammed ni Ikeja nipinlẹ Eko ni wọn maa balẹ si.

Oko ofurufu Air Peace lo n ko wọn bọ pada sile.

Wọn ni awọn oṣiṣẹ ẹnu bode South Africa lo da wọn duro ti wọn ṣẹṣẹ\tun n bẹrẹ ayẹwo tuntutn fun wọn.

Obinrin mẹtalelọgọrin ni Abikẹ Dabiri ni o wa ninu wọn.

Abikẹ Dabiri jiṣẹ erongba ijọba Naijiria fawọn ti wọn n bọ lati South Africa:

Ìjọba ti ṣetán láti tọ́jú àwọn ọmọ Naijiria tó ń bọ padà láti South Africa

A ṣi n reti wọn ki wọn de layọ ni adura -Abike Dabiri.

Loni ni Naijiria n reti awọn ọmọ Naijiria ti wọn n pada bọ wale fun irinajo abala akọkọ.

Lẹyin ikọlu lorisirisi ni South Africa ni Naijiria ni ki awọn ọmọ rẹ ti wọn ba fẹ pada sile ki wọn maa bọÀbábọ̀ mi sí orílẹ̀èdè South Africa rè é - Aṣojú Buhari.

Abike Dabiri Erewa to jẹ alaga ajọ to n mojuto ọrọ awọn ọmọ Naijiria nilẹ okeere ṣalaye ohun ti ijọba ni fun won ti wọn ba kọkọ de sile.

Abike Dabiri Erewa ni ijọba ti pese owo to to ogoji ẹgbẹrun sori ẹrọ ibanisọrọ ẹni kọọkan ki wọn fi kọkọ pe ẹbi ara ati ọrẹ wọn.

Bakan naa lo mẹnuba ipese owo okowo lati Bank of Industry Naijiria fawọn to fẹ bẹrẹ òwò nile ati iṣẹ ọwọ́.

Dabiri parọwa fawon ọmọ Naijiria loke okun ki wọn maa huwa rere ti yoo gbe ogo Naijiria ga nibikibi ti wọn ba wa.

O ni ki wọn ṣọra fun iwa abuku ati iwa idọti 'Operation Rewire' EFCC / FBI sèso owó tó lè ní mílíọ̀nù N153