South West Security -Ètò ìdaàbòbò ilẹ Yorùbá ti bẹrẹ -OPC

Image copyright @GAdams
Àkọlé àwòrán OPC Agbekoya setan fun aabo ilẹ Yoruba

Apapọ ẹgbẹ OPC, atawọn fijilante VGC, Agbẹkọya ati awọn miran ti bẹrẹ eto aabo alajumọse ni ilẹ Yoruba lati pese aabo to peye.

Agbarijọpọ awọn ẹgbẹ yii ni wọn ṣe ipade naa lọjọọru pẹlu awọn ti ọrọ kan lawujọ kaakari ilẹ kaarọ oojiire.

Wọn ṣe e lalaye pe, eyi jẹ ọna kan gboogi lati kin akitiyan awọn gomina ati ti ajọ Ọlọpaa ilẹ yii lẹyin lori eto aabo.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita leyin ipade akọkọ iru rẹ ti Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ṣe agbatẹru rẹni wọn ti sọrọ yii.

Nibẹ ni agbarijọpọ awọn ẹgbẹ naa ti rọ Aarẹ Ona kakanfo ki o lo ipo rẹ lati mu ibaṣepo to dan mọran wa sii laarin awọn lọbalọba ilẹ Yoruba.

Atẹjade ti ọkọọkan awọn olori ẹgbẹ naa bu ọwọ lu lojuna ati mu irẹpọ, ifẹ ati alaafia ba gbogbo ajọ eleto aabo kaakakiri ilẹ Yoruba.

Image copyright @PFN
Àkọlé àwòrán Olopaa gbaradi fun eto abo ile Yoruba

Koko atẹjade naa da lori ilanilọyẹ awọn ẹgbẹ kọọkan lati maa ṣe gbẹyin bẹbọjẹ ati lati sowọpọ pelu ajọ Olọpaa fun idaabobo to peye.

Ninu ọrọ rẹ, Iba Gani Adams pe fun ajọ to ni ironu piwada laarin gbogbo lajọlajọ lati pawọpọ gbe eto abo ilẹ yii larugẹ.

Aarẹ naa tesiwaju pe oun rọ gbogbo tolori tẹlẹmu lati gbaruku ti awọn agbofinro wa gbogbo ninu didaabo bo ẹmi ati dukia araalu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSuicide Prevention: ìwọ́de yìí wáyé láti gbógun ti pípa ara ẹni