Xenophobia; South Africa yóò pàdánù púpọ tí ó bá ní ìdojúkọ pẹlu ilẹ Naijiria - Ọjọgbọn Ndubuisi.

Àkọlé àwòrán Awon omo Nigeria to de lati S/A

Ṣe Yoruba bọ wọn ni, ajo ko le dun titi ko dabi ile, eyi ni orin to gba ẹnu awọn ọmọ orilẹ-ede yii to de pada lati ilẹ South Africa.

Awọn ọmọ Naijiria mejidinlaadọwa ni wọn pada de si papakọ ofurufu ilu Eko lana ti wọn si n fo fayọ fun idasi ẹmi wọn.

Ṣugbọn awọn eniyan ti bẹrẹ si n beere wi pe kini yoo jẹ igbaye gbadun awọn ti o ṣẹsẹ de pada yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionXenophobia: Naijiria á kọ́kọ́ pèsè ọ̀nà láti bá ẹbí sọ̀rọ̀ fún wọn

Abikẹ Dabiri Erewa ti o jẹ Alaga ajọ ti o n ri si ọrọ ọmọ Naijiria loke okun ti ṣalaye pe, eto ti wa nilẹ lati fun wọn ni iranlọwọ owo fun okoowo .

Sẹ saaju ni Aarẹ Buhari ti paṣẹ ikopada bọ awọn ọmọ Naijiria ti o ba nifẹ lati wale lati orilẹ ede naa, ti awọn to to bii ẹgbẹta si ti forukọ silẹ.

Koko idi tawọn ọmọ Naijiria ṣe n wa iṣẹ aje lọ si orilẹ-ede miran ni nitori pe ọrọ aje wa to dẹnu kọle ni Naijiria.

Oriṣiriṣi ibeere lo wa n jẹ yọ pe, n jẹ Naijiria tilẹ ni igboya lati koju Ilẹ South Africa.

Lori eyi, ọga agba fun eto idokowo fun orilẹ ede yii ati South Africa, Foluṣọ Philips dahun wi pe, okoowo nikan ni ibaṣepọ laarin orilẹ-ede mejeeji.

O fikun un pe, yatọ si epo rọbi ti orilẹ-ede yii n ta fun wọn, iṣẹ iranlọwọ to peye ti awọn ọmọ Naijiria n sẹ fun wọn ko kere rara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionXenophobia: Awọn ọmọ Naijiria n sọ ohun tó kàn lẹ́yìn ìpadàbọ̀ wọn

O le ni ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin awọn ọmọ Naijiria ti wọn ni wọn fi South Africa ṣe ibujoko wọn ṣaaju ikọlu yii gẹgẹ bi Nigeria union South Africa (NUSA) ṣe sọ.

Alaga ileeṣẹ ọkọ ofurufu Air Peace, Allen Onyeama lo gbe ọkọ ofurufu Air Peace lati fi ko awọn ọmọ NAijiria ti wọn ba fẹ pada wa sile lọfẹẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSuicide Prevention: ìwọ́de yìí wáyé láti gbógun ti pípa ara ẹni

Ibeere nla ti awọn eniyan n beere ni pe ṣe Naijiria too ba South Africa ja ija lodi si ikọlu yii?

Foluṣọ Phillips dahun ibeere yii fun BBC pe ti a ba yọ ti ọja tita ati rira kuro, ko si ajọṣepọ korikosun kankan laarin orilẹ-ede mejeeji.

O ni Naijiria n ta epo rọbi fun South Africa ni eyi ti awọn naa n ta ohun eelo ninu ile fun Naijiria.

Foluṣọ tun sọrọ lori ipa awọn akọṣẹmọṣẹ ọmọ Naijria n ko ni South Africa ti ko ṣee fi ṣere rara.

Bakan naa ni Ọjọgbọn kan ninu imọ eto ọrọ aje, Nwokoma Ndubuisi ba BBC sọrọ lori koko yii.

Nwokoma ṣalaye pe orilẹ-ede South Africa ni yoo mọọ lara ju ti ede aiyede ba be sile laarin awọn mejeeji.

O ni awọn mejeeji ni yoo mọ pe nkan sọnu lọwọ wọn ti ija ba de ṣugbọn yoo fi si okowo South Africa ju ti Naijiria lọ.