Àrà ni mí; èmi kìí ṣe Àrá -Àyánbìnrin Aralola Olamuyiwa
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ara: Láti kékeré ni mo ti ń lu ìlú pẹ̀lú ayọ̀

Emi gangan ni Àrà -Aralola.

Àrà rèé, ogbontarigi ayanbinrin ti gbogbo eeyan mọ pẹlu ilu lilu kaakiri agbaye.

O ba BBC Yoruba sọrọ lori bi oun ṣe bẹrẹ lati kekere titi di ibi ti Ẹlẹda ran oun lọwọ de bayii.

Bakan naa ni Àrà ti orukọ rẹ n jẹ Aralọla Olamuyiwa lapeja sọrọ lori ọmọbinrin mii to n lu ilu bii tirẹ.

O ni Àrá ni orukọ ọmọ Igbo naa n jẹ ati pe ọna ilu lilu awọn yatọ sira wọn.

Ara sọrọ lori bi aisan ṣe sọ oun di olominira lọwọ baba oun ti ko kọkọ fẹ faramọ orin kikọ ati ilu lilu fun oun.

O rọ awọn ololufẹ rẹ lati má ṣi oun mu mọ fun Àrá nitori ọtọ ni tọ́lú ọtọ dẹ ni tọ̀lù ni awọn mejeeji.