Malaria: Wo ọ̀nà láti gbógun ti àìsàn Ibà lásìkò yìí

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹfọn kìí ṣe ọmọ rere fun agọ ara eniyan

Abọ iwadii kan lo fihan pe gbogbo agbaye lo maa wa ni inu wọn a dun ti ọrọ aisan Iba ba yọ kuro ni aye.

Aisan iba jẹ ọkan lara aisan to n gba ẹmi awọn eniyan pupọ lati ọdun mọ ọdun.

O le ni igba miliọnu igba ti iba n ṣe awọn eeyan agbaye paapaa awọn ọmọde lọdun.

Gbogbo awọn onimọ lo gba pe gbigbogun ti aisan yii yoo jẹ aṣeyọri nla ni agbaye.

Kini aisan iba?

Nkan kan ti àwọn oloyinbo n pe ni Plasmodium ni o n fa aisan iba.

Lati ara ẹni kan si ikeji ni o ti n tan kalẹ lasiko to ba n mu ẹjẹ gẹgẹ bii ounjẹ.

Kete to ba ti pọ oro yii sini lara ni ẹni naa ma ni aisan iba ni eyi to maa n ṣiṣẹ akọ lori ẹdọ ati ẹjẹ eniyan.

Nigba to ba ti din agbara inu ẹjẹ ku tan lo maa wo gbogbo agọ ara eniyan palẹ ni eyi to le ja si iku.

O le ni akọsilẹ iku marindinlogoji le ni irinwo awọn eeyan paapaa awọn ọmọde ti o n ṣẹlẹ lọdọọdun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionO tó ìdá méjì àwọn ènìyàn àgbáyé to wà nínú ewu àìsàn ibà

Kini o n ṣẹlẹ bayii lori aisan iba?

Aṣeyọri ti wa lati gbogun ti aisan iba.

Lati ọdun 2000 ni wiwọpọ aisan iba ti dinku lati ida 106 si 86.

Bakan naa ni ọna nini ti dinku si ida mẹrindinlogoji ninu ọgọrun un ati pe iku awọn ọmọde naa ti dinku lori aisan iba.

Ọpọlọpọ oogun iba ni iṣẹ iwadii ti gbe jade ni eyi to ti gbogun ti aisan iba de aaye kan.

Sibẹ, oniṣegun oyinbo Winnioe Mpanju Shumbusho to jẹ ọkan lara awọn oluwadii yii ni o wọpọ julọ ni ilẹ Adulawọ nibi ti orilẹ-ede marun un ti ni to idaji ti agbaye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌ̀nà àbáyọ de láti gbẹ̀san lára Ẹ̀fọ̀n mùjẹ̀mùjẹ̀

Pataki ohun ti a fẹ ki ẹ mọ:

Ti a ba le sọ ọrọ aisan iba di afiẹyin ti eegun n fiṣọ yoo di ogo nla fun agbaye.

Ajọ iṣọkan lori ilera agbaye W H O sọrọ lori iye owo ti o ti ba aisan iba rin ni agbaye ati odiwọn iye owo to le fopin si aisan iba.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán WHO n woye odiwon iye owo ti o le fopin si aisan iba ni agbaye

Sir Richard Feachem, ọkan lara awọn to kọ iwe nipa fifopin si aisan iba titi ọdun 2050 n bi akọsilẹ yii ṣe fihan pe polio le dopin ni asiko yii naa ni wọn ni ẹri pe aisan iba le dopin ni 2050.

Wọn ni a nilo to biliọnu mẹrin o le owo dọla lati fi gbogun tii pẹlu afikun biliọnu dọla meji ko to dopin ni agbaye yatọ si ipese awọn oṣiṣẹ ati onimọ nipa rẹ.

Se lootọ ni a le fopin si aisan iba titi 2050 ni agbaye?

Ipenija nla ni eyi jẹ ni agbaye, ṣugbọn o ti ṣẹlẹ ri fun aisan igbona ni eyi ti o dopin ni ibẹrẹ 1980 fun saa kan.

Lẹyin ọdun mọkanlelogun ti iṣẹ ti n lọ lori polio ni o di pe ida mọkandinlọgọrun un lo ti fi tan ni agbaye.

Diẹ lo ku ki Naijiria ati Afirika lapapọ sọ aisan polio rọmọlapa rọmọlẹsẹ di afiẹyin ti eegun n fiṣọ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ko si ẹni ti ko le gbiyanju lati gbogun ti ẹfọn

Aarẹ WHO, oniṣegun oyinbo Tedros Ghebreyesus ni o ṣeeṣe ki aisan iba dopin nitori o ti jẹ ipenija ajọ iṣokan agbaye fun ọpọlọpọ ọdun.

Oniṣegun oyinbo Fred Binka ti fasiti Ghana sọrọ lori pataki gbigbogun ti aisan iba lagbaye.

O ni iṣẹ ṣi wa niwaju awọn oniṣegun oyinbo lati fọwọsowọpọ ninu iwadii ati ninu iṣẹ oogun to n gbogun ti aisan iba lagbaye.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn ọmọde ni aisan yii n ba firan julọ

Erongba awọn onimọ ni pe, titi ti agbaye yoo fi ojutu patapata si aisan iba, ki onikaluku ṣi maa gbe igbeṣẹ imọto ti o yẹ ni ayika.

Ki awọn eeyan rii pe ẹfọn ko jẹ wọn de ibi to maa pọ oro aisan iba si wọn lara.

Ki ẹni to ba ni iba tete lọ fun itọju nile iwosan.

Ki gbogbo orilẹ-ede ṣetan lati fọwọsowọpọ ninu iṣẹ iwadii naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSuicide Prevention: ìwọ́de yìí wáyé láti gbógun ti pípa ara ẹni