Election Tribunal - Egbé wa ni yóò jáwé olúborí ni ile ẹjọ gíga jùlọ - PDP.

Aworan PDP Image copyright @PDP
Àkọlé àwòrán Awọn agbẹjọro wa gbiyanju, ṣugbọn ...

Awọn eeyan n ro pe agbẹjọro Atiku ko ṣiṣẹ iwadii wọn tó.

Latari abọ igbẹjọ ile- ẹjọ ti o n ri si eto idibo laarin ẹgbẹ APC ati PDP, awọn araalu bu ẹnu atẹ lu agbẹjọro PDP.

Wọn ni aikunjuwọn iwadii awọn agbẹjọro naa ni ko jẹ ki wọn boriÀwọn ọmọ Naijiria sọ̀rọ̀ lórí ìgbẹ́jọ́ tó da ẹjọ́ Atiku nù! ,sugbọn ti abẹnugan ẹgbẹ oṣelu PDP, Kọla Ọlọgbọndiyan ni ko ri bẹẹ.

Nigba ti o n fesi si ọrọ naa fun ile iṣẹ BBC, o ni, wọn ṣe akitiyan pupọ debi pe, awọn agbẹjọro keji ni lati salọ kuro nile ẹjọ.

Lori ọrọ gomina Wike ti ipinlẹ Rivers pe o ki Buhari ku orire, Ọlọgbọndiyan ni, àwọn ko tii ṣe iwadii eyi rara lasiko ti BBC pe.

Ẹgbẹ PDP wa ni idaniloju wa pe awọn yoo ja ewe olubori ninu igbẹjọ ti wọn yoo pe si ile ejọ giga julọ laipe.

O ni Ọlọrun ọba nikan loni idajọ ododo ti yoo si ṣe idajọ to peye fun ẹgbẹ PDP.

Image copyright @APC
Àkọlé àwòrán APC jawe olubori ni igbejo idibo aarẹ