Aṣíwájú ilẹ̀ Yorùbá tuntun sí ọmọ Yorùbá-Tọwọ́ tẹsẹ̀ ni mo fi gba ipò yìí

Aworan ọjọgbon Akintoye ati awọn asaju Yoruba miran
Àkọlé àwòrán Gbogbo ohun ti Afẹnifẹrẹ mu ni pataki ni ẹmi naa yan laayo

Oun ti o yẹ ka gbaju mọ lasiko yi ni isọkan awa Yoruba.

Koko pataki to jẹ yọ re lati inu ọrọ akọkọ ti ọjọgbọn Banji Akintoye fi sita lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ nilu Eko.

Gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ ilẹ̀ káàrọ́ọ̀-òò-jíire jakejado agbaye (Assembly of All Yoruba Groups, Worldwide) lo ṣaaju dibo yan Akintoye gẹgẹ bii asaaju ọmọ ilẹ Yoruba loṣu kẹjọ ọdun yi.

Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ Akintoye ni oun gba oye naa tọwọ tẹsẹ ti o si pe fun ifọwọsowọpọ awọn ọmọ Yoruba.

Ọjọgbọn Banji ni o ṣe pataki lati wo awọn ipenija to n doju kọ ilẹ Yoruba paapa julọ eleyi to ni ṣe pẹlu aabo.

O ni inu ibẹrubojo lawọn eeyan wa amọ awọn ọmọ Yoruba ko ṣe ''ojo lati doju kọ awọn to fẹ gba ilẹ mọ wọn lọwọ''

Bakanna lo sọ pe iran Yoruba yoo jẹwọ orukọ wọn gẹgẹ bi wọn ti ṣe ṣe saaju ọdun 1840 nigba ti awọn kan fẹ kogun ja wọn.

Laipẹ́ yi ni awọn igun ẹgbẹ asaaju Yoruba kan n sọ pe ọjọgbọn Akintoye ti kọ ipo ti wn yan si.

Ohun ati Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ni wọn jijọ du ipo yi ki o to ja mọ lọwọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: