Assurance 2020: Davido ní kí àwọn olólùfẹ́ òun fi ojú sọ́nà fún ìgbẹ́yàwó òun pẹ̀lú Chioma

Chioma ati Davido lọ mọ ara wọn Image copyright @iam_Davido

Idunnu ati ayọ ni awọn ololufẹ David Adedeji Adeleke, ti gbogbo eniyan mọ si Davido fi gba iroyin pe Chioma ti gba lati fẹ oun.

Ninu fidio kan ti wọn fi si ori ẹrọ ayelujara ni Davido ti kunlẹ lori ẹsẹ kan lati fun ololufẹ rẹ ni oruka ifẹ lati beere owo rẹ ni igbeyawo.

Bakan naa ni Chioma ti fi lede lori oju opo instagram rẹ wi pe, oun fẹran Davido tọkantọkan.

Amọ, ọpọlọpọ awọn eniyan ni ko mọ awọn nkan pato nipa Davido, ọmọ baba olowo.

Ǹkan márùn ún tó yẹ kó o mọ̀ nípa Davido

 • Oruko ti wọn sọ Davido ni David Adedeji Adeleke ni Atlanta lorilẹede Amẹrika ti wọn bi si, amọ ti o si dagba si ilu Eko
 • Ọdun mọkanla ni Davido wa nigba ti iya rẹ jade laye ni ẹni ọdun mọkandinlogoji
 • Davido fi ifẹ rẹ fun iya rẹ han lẹyin ti o sọ orukọ ọmọ rẹ mejeeji to bi ni Imade ati Veronica, tii se orukọ iya rẹ
 • Obinrin meji (Sophia Momodu ati Amanda) lo ti bi ọmọ fun Davido, amọ Chioma to jẹ aayo Davido bayii naa ti diwọ-disẹ sinu
 • Ọdun mẹfa ni Davido ati Chioma ti n fẹ ara wọn, ki Davido to beere pe ki Chioma fẹ oun, to si ti yọju sile wọn lati tọrọ rẹ
 • Davido ra mọto ayọkẹlẹ kan fun Chioma, eyi to pe ni Assurance nigba ti obinrin naa pe ẹni ọ̀un mẹtalelogun losu kẹrin lọdun 2018
 • Bakan naa lo se awo orin kan jade, eyi to fi sọri Chioma, to si pe awo orin naa ni Assurance
 • Ọpọ igba ni Chioma ati Davido ti jọ rinrin ajo yika agbaye, ti wọn si ti de ọpọ orilẹede
 • Davido lọ si ile-iwe British International School nilu Eko, ko to lọ si orilẹede Amerika lati lo kọ ẹkọ imọ eto ọrọ aje, amọ ifẹ rẹ fun orin kikọ mu ki o kuro ni fasiti naa, ti o si kọ ẹkọ gboye ni ile iwe fasiti Babcock ni ọdun 2015
 • Lati ile iwe giga, Oakwood ni Davido ti bẹrẹ orin kikọ pẹlu Sina Rambo ati awọn akọrin ikọ KB
 • Iroyin kan ti ko fidi mulẹ, to n ja lori ayelujara ni pe Davido ni dukia ati owo to to ọgbọn biliọnu naira
 • Ọpọlọpọ awo orin ni Davido ti kọ, bakan naa ni lo n gbe orin jade fun awọn akọrin ti wọn ba sẹsẹ n gberi.