Iná jó ọjà Ògùnpa ní Ibadan
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ogunpa Fire: Ọjà olówó iyebíye jóná lọ́jà Ogunpa

Ariwo aje o, owo o, lo gba ọja Ogunpa nilu Ibadan kan lowurọ ọjọ Satide nigba ti apa kan isọ awọn to n ta ohun elo iranṣọ jona.

Gẹgẹ bi iroyin ti a gbọ ṣe sọ, ko din ni ṣọọbu itaja bii mẹwa to fara kaasa iṣẹlẹ naa.

Iroyin o ṣe oju mi koro ti a gbọ jẹ ko di mimọ pe, o ṣeeṣe ko jẹ pe ọkan lara awọn ṣọọbu itaja naa ni ko pa ina ọba nigba ti wọn pari karakata tan lọjọ Ẹti.

Ina ọba to gbina ninu ọkan lara awọn sọọbu naa lo ran awọn yooku rẹ.

Gẹgẹ bi a tun ṣe gbọ, awọn ohun elo ẹṣọ aṣọ atawọn aṣọ olowo iyebiye lo jona ninu iṣẹlẹ ijamba ina naa.

Itaraṣaṣa awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana ipinlẹ Ọyọ ti wọn pe, ni ko jẹ ki ọṣẹ ti ina naa ṣe pọ ju bi o ti mọ lọ.

Titi di bi a ṣe n sọrọ yii, ko tii si ẹni to lee sọ ni pato ohun gan an to fa iṣẹlẹ naa.