Dòkítà tó ṣe iṣẹ́ abẹ fún ọlẹ̀ inú l‘Amẹrika ló ń sọ Yorùbá yìí bíi ẹní la oyin
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Olutoye: Ọmọ ọdọ̀ àgbà ni mí, kò sì yẹ kí èdè Yorùbá parun

Ogo ọmọ Yoruba kan ree to jẹ amuyangan lorilẹ aye.

Dokita Oluyinka Olutoye, ẹni to se isẹ abẹ fun ọlẹ inu alaboyun lorilẹ ede Amẹrika ba BBC Yoruba sọrọ lori eto ilera, ihuwasi awọn sms Naijiria loke okun ati agbelarugẹ asa Yoruba.

Dokita onisẹ abẹ naa ni awọn ọlọpọlọ pipe pọ ni Naijiria, amọ awọn ohun eelo ti wọn yoo fi sisẹ ni ko si ni arọwọto wọn.

O wa rọ ijọba Naijiria lati pese awọn ohun eelo to yẹ fun awọn dokita lati sisẹ, ki awọn naa lee lu aluyọ bii ti oun lẹka eto ilera.

Lori agbelarugẹ asa Yoruba, Olutoye gba awọn ọmọ Yoruba nimọran lati maa kọ awọn ọmọ wa ni ede abinibi wa, ko maa baa parun.

Olutoye, ẹni to sọ ede Yoruba bii ẹni la oyin ni ọmọ ọdọ agba ni oun, ti oun ko si lee gbagbe ile.

Ẹ wo ẹkunrẹrẹ ọrọ ti ilumọọka dokita naa, to n dari ile iwosan nla ni lorilẹede Amẹrika ti wi.