Accident: Eré àsápajúdé la gbọ́ pé ó fa ìjàǹbá ọkọ̀ náà

Ijanba ọkọ Image copyright Others

Eeyan kan tun ti padanu ẹmi rẹ ninu ijamba ọks to waye ni owurọ oni ọjọ Isẹgun lopopona Ibadan silu Eko.

Iroyin naa ni adugbo ti fasiti Christopher wa, ka to wọ inu Eko lẹba ilu Sagamu ni ijanba naa ti waye.

Nigba to n fi idi isẹlẹ yii mulẹ, Oludari ajọ to n mojuto akoso oju popo FRSC nipinlẹ Ogun, Clement Oladele ni ọkọ akero kan n bọ lati Ibadan lo fori sọta ijanba ọhun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọladele ni ọkọ naa, to n sare asapajude lo sadede lọ fori sọ ọkọ nla kan ti wọn gbe silẹ lẹba oju popo marosẹ naa, ti eeyan kan si jẹ alaisi.

O fikun pe, saka ni ara awọn eeyan yoku to wa ninu mọto naa da, ti wọn ko si fi ara gba ọgbẹ kankan bi ti wu ko mọ.

Ọga agba fun ajọ FRSC nipinlẹ Ogun ni ijanba yii ko fi bẹẹ sokunfa sunkẹ-fakẹrẹ ọkọ, ti awọn ọkọ si n kọja geerege lopopona naa bayii lai si idiwọ kankan.