Kwara: AdbulRahman Adbulrazaq fi orúkọ àgùnbánirọ ránṣé si ilé ìgbìmọ Aṣofin.

Gómìnà ìpínlẹ Kwara Adbulrahman Image copyright facebookpage adbulrahman

Gomina lpinlẹ Kwara,AbdulRahman AbdulRazaq ti fi oruko ọmọ ọdun Mẹrindinlọgbọn sọwọ si ile igbimọ asofin ipinlẹ gẹgẹ bi kọmiṣanna ni ipinlẹ naa.

Joana Nnazua Kolo, ẹni ti o ṣii n ṣiṣẹ sin orilẹede yii gẹgẹ bi Agunbanirọ ni ipinlẹ Jigawa,n ṣiṣẹ olukọni ni ilu naa.

Ile igbimọ Aṣofin ilẹ Kwara ti ṣalaye wi pe, wọn yoo ṣe ayẹwo finifini fun awọn ojugbaa rẹ ti wọn yan pelu u rẹ.

Omidan Kolo, ni yoo jẹ kọmiṣanna ti ọjọ ori i rẹ kere julọ ninu awọn oloṣelu ilẹ Naijiria.

Ṣe ni oṣu kan abọ sẹyin ni gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde yan ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn sinu eto iṣejọba rẹ.

O jẹ akẹkọọ jade ile iwe fasiti ti ipinlẹ Kwara ti o si kẹkọọ gboye lori imọ ijinlẹ sayẹnsi ikowepamọsi.

Bo ti lẹ jẹ pe, awọn miiran wa ti o jẹ obinrin ti gomina naa yan sugbọn, Omidan Kolo ni o kere julọ.

Elomiran ni Iyaafin Folashade Ọmọniyi, ti o jẹ oludari agba tẹlẹ fun ile ifowopamọ banki Akọkọ[First Bank] fun ipawowọle.

Ọmoniyi kẹkọ gboye imọ Erọ ni Yunifasiti ti ilu llọrin ti o si ni ọpọlọpọ iwe ẹri miiran ni ilẹ yii ati oke okun.

Bakan naa ni Iyaafin Sa'adatu Moddibo- Kawu ti o kẹkọ gboye lori ọrọ Aje ni Yunifasiti ti Usman Danfodio,Sokoto,pelu ọpọ iwe eri miran.

Aarinọla Fatimoh Lawal ẹni ti o kẹkọọ gboye ni ọdun 1993 ni ile Ẹkọ gbogboniṣe ti ipinlẹ Kwara lori imọ nipa ile itura ati ina dida.

Nigba ti Aisha Ahman-Pategi jẹ ogbona gbongbo nipa eto ọrọ aje ti o si kẹkọọ gboye ni Yunifasiti Ahmadu Bello,Zaria, ni lpinlẹ Kaduna.

Related Topics