'Àwọn èèyàn máa ń rò pé dúdú ni mo fi ń pidán', kí wá ni ọmọ ọdún 19 yìí ń lò?
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Babs Magician: Láti ọmọ ọdún márùn-ún ni mo ti fẹ́ràn láti máa pidán

Bi ala ni idan maa n ri loju awọn eeyan ti awọn mii ti ko bikita si gba pe irọ gbaa ni idan pipa.

Ṣugbọn ni ti Babs Cardini, Akoroyin BBC, Joshua Akinyemi bá a rin lojuna iṣẹ idan pipa rẹ lati fi han awọn eeyan boya o n bọ si i tabi o n yiwọ.

Babs ni o ti maa n wu ohun lati jẹ apidan nigba to wa ni ọmọ ọdun marun-un o si ri i daju pe o yan an laayo.

Erongba Babs ni lati di apidan to lorukọ ju lagbaye.